South Africa: Oyún inú nínú ilé ìgbọ̀nsẹ ọkọ̀ bàálú tó fẹ rinrin àjò

Inside plane Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán South Africa: Oyún inú nínú ilé ìgbọ̀nsẹ ọkọ̀ bàálú tó fẹ rinrin àjò

Ó jọ bi ẹ ni pe ẹni kan to ni oyún ti kò fẹ ọmọ ti yọ oyun ọmọ náà si inú ilé ìgbẹ́ inú ọkọ òfurufú.

Ní orílẹ̀-èdè South Africa ni ọkọ̀ òfurufú tó n lọ lati ìlú Durban si Johannesburg ti di ilé igbẹbi fún ikoko kan.

Lojiji ní ọkan lára àwọn tó ń tójú àyíka ke gbàjare lẹ́yìn to lọ toju ọkọ̀ bàálu ti yóò rin ìrìn ajo ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEbola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀

Alaṣẹ Ọkọ̀ ofúrúfu Fly Safari sọ nínú àtẹjade rẹ lori ẹrọ alátagbà wọn pé inu ilé igbẹ ni wọ́n ti ri ẹjẹ ọrun tuntun ọ̀hun, èyí to si nílò ìwádìí nílànà òfin.

Image copyright @flysafariofficial
Àkọlé àwòrán South Africa: Oyún inú nínú ilé ìgbọ̀nsẹ ọkọ̀ bàálú tó fẹ rinrin àjò

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ó jọ bi ẹni pé ẹnikan ń gbìyànjú láti ma jẹ ki ẹnikẹni mọ pé òún bímọ.

Agbenusọ fawọn agbofinro ni South Africa, Thembeka Mbele ni ọrọ naa jọni lọju gidi ṣugbọn iṣẹ iwadii ṣi n lọ.

Ìròyìn sọ pé ọkọ ofurufu náà ti balẹ̀ sí Durban láti alẹ ọjọbọ lẹ́yìn to tààjò dé láti Johannesburg.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAFCON 2019: Inú mi dùn pé mo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó ṣojú Nàíjíríà fún ìgbà 100