Super Falcons: Iṣẹ́ ẹmí ẹtan ló bàlemi lasiko tí mọ so aṣọtẹlẹ̀ pé wọn ó wọ ipele aṣekágbá.

Super FAlcons
Àkọlé àwòrán,

Akọ̀wé ẹgbẹ́ CAN ní ìpínlẹ̀ Ebonyi nígbà kan ri tí wá rọ ọmọ Nàìjíríà láti fi ori jí òun ati pé òun yóò ma kíyèsára ní ìgbà míràn.

Ẹ darijin mi, ẹ̀mí ẹ̀tàn ló lò mí -Pasitọ.

Ìlúmọọka Olúsọagutan Simeon Ononogbu ní ẹmi ẹ̀tàn ló bàlé òun lásìkò ti òun n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons.

O ni pé àwọn ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù obinrin Nàìjíríà yóó wọ́ ipele tó kángun sí àṣekágbá nínú ìdíjẹ ifé ẹ̀yẹ àgbáyé tawọn obinrin tó n lọ lọ́wọ́ ní France.

Gẹ́gẹ́ bi akọròyìn NAN sẹ sọ, ẹni ọ̀wọ̀ Simeon Ononogbu sọ sáa'ju idije ife ẹ̀yẹ àgbáyé pé ikọ Super Falcos yóò de ipele tó kangun si aṣekágbá.

Bakan naa lo ni France to ń gba alèjò ayẹyẹ náà wà ni ipò kaàrún tọ jẹ ipele kéta si aṣekágbá.

Àkọlé fídíò,

Iná Ibadan: Gbogbo dúkìá tó wà lókè ilé alájà kan náà ló jóná tán

Akọ̀wé ẹgbẹ́ CAN ní ìpínlẹ̀ Ebonyi nígbà kan ri tí wá rọ ọmọ Nàìjíríà láti fi ori jí òun ati pé òun yóò ma kíyèsára ní ìgbà míràn.

O ní " ó ṣeni láànú pé asọtlẹ̀ mi lóri Super Falcons kùnà, èyí túmọ si pé ìsípaya náà kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run."

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

Pasitọ yii ni: "Ọ̀pọ̀ ẹ̀mi ló n rìn kiri ti yóò ma tan àwọn ènìyàn jẹ ká ti ènìyàn kò bá kíyèsára gẹ́gẹ́ bi irú èyí"

Ononogbu tún tẹnpẹlẹ mọ́ọ pé bi asọtẹ́lẹ̀ nípa Super Falcons tilẹ kùna òun túbọ dúro lóri ipò ti France yóò kangun sí

Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ma dá oun lẹ́jọ nitori ọ̀rọ̀ yìí nítori pé òun ti sọ asọtẹ́lẹ̀ mẹ́jọ ọtọ̀ọ̀tọ tó ti jási òòtọ́.

Àkọlé fídíò,

Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Kini èrò ajọ CAN ọmọlẹyin Kristi lori asọtẹlẹ ẹ̀tàn:

Ẹ̀wẹ̀, BBC Yoruba kan si ẹgbẹ́ adarí awọn ọmọ lẹ́yìn Kristi (CAN), Ẹni ọ̀wọ̀ Bayo Oladeji lóri èrò wan lóri isọtẹ́lẹ̀ ti kó wá si ìmúṣẹ ỌHUN.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Iṣẹ́ ẹmí ẹtan ló bàlemi lasikọ tí mọ so aṣọtẹlẹ̀ pé wọn o wọ ipele aṣekágbá.

Oluṣọ agutan naa ni àwọn kìí sọrọ̀ lóri ìrírí olúkulúkù nítori onikaluku lọ mọ apá ibi ti wọ́n ti n gbọ́ ìmísi.

O ní ọ̀nà ti àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi yóò fi ri ìtójú gbà lọ́dọ̀ ìjọba lo jẹ ajọ CAN lógun jùlọ, èyí si ni àwón maa n múgbọ.

Oluṣoagutan yii ni onikaluku lo mọ iru ìpè ti oun gbà ati iṣẹ ti Oluwa ran oun lati ṣe.

Àkọlé fídíò,

Ebola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀