Ko sẹ́ni tí yóó dan 'Ruga settlement' wò nílẹ̀ Yoruba - Ìgbìmọ̀ àgbà Yoruba
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ruga settlement: YCE ní ìjọba àpapọ̀ kò tó bẹ̀ẹ́ láti kọ́ àgọ́ Fulani sílẹ̀ Yoruba

Lẹ́yìn awuyewuye tó ń ṣẹ̀lẹ̀ lórí ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ àgọ́ Fulani ti wọ́n pè ní 'Ruga settlement' ní Ipinlẹ Benue, Ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà Yorùbá ti fèsì.

Bó tilẹ jẹ́ pe awọn olùgbe Ipinlé naa kọ̀ ọ́, Ìgbìmọ̀ Àgbààgbà Yoruba (YCE) ti ní bí ìjọba àpapọ̀ bá dán irú rẹ̀ wò nílẹ̀ káàrọ̀ o jíire, yoo dan an tán.

Akọ̀wé àgbà ìgbimọ náà, Dokita Kunle Olajide ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lori ọ̀rọ̀ náà.