US-North Korea: Trump ati Kim John-un padé ni DM Zone

Trump ati Kim Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán US-North Korea: Trump ati Kim John-un padé ni DM Zone lati bere ìpàdé

US-North Korea: Trump ati Kim John-un ti ṣe ìpàdé.

Lẹyin ipade aarẹ Amerika, Donald Trump ati Kim Jong Un ni ori ilẹ North Korea ni Trump ti ki ara rẹ ku iṣẹ takuntakun ti o ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIraq, Palestine wà nínú orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ìwádìí BBC ti wáyé

Aarẹ Trump ni oun ati aarẹ Moon ti fẹnuko lori adehun okowo tuntun ti yoo bi eso rere fawọn orilẹ-ede mejeeji.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ipade alaafia pẹlu Moon, Kim ati Trump yoo bi eso rere

Aarẹ South Korea, Moon Jae-in naa darapọ mọ KIm Jong Un ati Donald Trump ni DMZone ti won ti pade.

Moon ni ipade yii yoo so dundun fawọn eniyan Korean Pennisula.

Ki lo ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Nínú ìpàdé ti wọ́n ṣe kẹ́yin, wọ́n kò fẹ́nu ọ̀rọ̀ jóná lóri ọ̀nà ati dáwọ́ agbékalẹ ọ̀rọ̀ ǹkan ìjà ogun ti North Korea n gbèrò láti ṣe.

Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika Donald Trump di ààrẹ àkọkọ lóri àléfà ti yóò wọ ilẹ̀ North Korea lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú Kim Jung-un ní ojú ààla to pí prílẹ̀-èdè Korea méjèèjì tí wan ń pe Demilitariksed Zone (DMZ).

Ọ̀pọ̀ àwọn kan ní eré oritage ninu òṣèlú lásán ni nígbà ti àwọn míràn gbàgbọ́ pé èyí yóò lánà fún ìtàkurọsọ tí yóò ṣe ànfani lọ́jọ́ iwájú.

Nínú ìpàdé ti wọ́n ṣe kẹ́yin , wọ́n o fẹ́nu ọ̀rọ̀ jóna lóri ọ̀nà ati dáwọ agbékalẹ ọ̀rọ́ ǹkan ìjà ogun ti North Korea n gbèrò lati ṣe.

Lásìkò ti Trump ń ba àwọn oníroyin sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Kim lẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, o ní Malegbagbé ni ìpàdé àwọn inú òun si dùn láti dá ilà ààrin North Korea àti South Korea koja>

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJohn Ogu bá BBC Yorúbá sọ̀rọ̀ lórí ìgbáradì Nigeria vs Madagascar

Ní ti Kim niti rẹ ó ni ipade pọ àwọn jẹ́ ohun àmi fún ńkan ti o tayọ.

Sááju ni àwọn Trump ti pe ipade pẹlu Kim láti dáwọ ipinnu rẹ dúro lóri èrongba rẹ lati ṣe ifilọlẹ ohun ija olóro ní orilẹ̀-èdè Singapore ni èyi to fori sọnpọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá