Òsìsẹ́ Custom tó wọ asọ Ọ̀gá Àgbà CG ti wà ní ile iwosan!

Custom Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Iroyin gbe e jade wi pe osisẹ to wa ni ipo Assistant Superintendent wa si olu ile isẹ naa pẹlu aso oye Comptroller-General.

Osisẹ ile isẹ asọbode orilẹede Naijiria, Assistant Superintendent Nura Dahiru ti wa ni ile iwosan bayii, lẹyin to wa si olu ile isẹ naa pẹlu asọ ọga patapata to si kede ara rẹ gẹgẹ bii ọga patapata "Comptroller-General".

Iroyin ni arakunrin naa bẹrẹ si ni sọ kantan kantan wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo pa asẹ fun oun lati wa gba isẹ lọwọ Ọga Agba Ajọ Custom patapata, CG, Hameed Ali.

Agbẹnusọ fun ile isẹ Custom, Joseph Attah lo fidi eyi mulẹ lasiko to n ba BBC sọrọ.

Attah ni ọrọ osisẹ naa ko ba ara wọn mu ni awọn se pe dokita lati wa se ayẹwo fun ọkunrin naa, ti o si ti wa ni ile iwosan lọwọlọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀