PDP Osun: A fẹ́ fún Ademola Adeleke ní tíkẹ́ẹ́tì ọ̀fẹ́ láti díje dupò gómìnà ní 2022

Ademola Adeleke Image copyright Ademola Adeleke

Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ọsun, Soji Adagunodo ti fesi lori ọrọ ti ẹgbọn Ademọla Adeleke, eyiun Deji sọ lori ibo gomina Ọṣun lọdun 2022.

Deji Adeleke lo sọ wi pe, Sẹnetọ Adeleke fẹ sinmi fun igba diẹ, nitorina, ki ẹgbẹ oselu PDP dawọ duro lori ero wọn lati fa a silẹ gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina ni ọdun mẹrin si isinyi.

Nigba to n fesi si ọrọ naa, Adagunodo salaye pe PDP yoo lo ẹbi ati ara Adeleke fun idije si ipo oselu ni ipinlẹ naa nitori wọn ni ero to pọ lẹyin wọn, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Soji Adagunodo fikun wi pe, kii se adari ẹgbẹ lo n yan ẹnikẹni lati dije dupo, amọ awọn eniyan to ba ni ọmọlẹyin to pọju, nitori ẹni ti wọn ba di ibo fun ni awọn ma a gbe si iwaju.

Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Osun naa wa fikun wi pe, o ti ye gbogbo ẹgbẹ patapata ipo ti Ademọla Adeleke wa ninu ẹgbẹ, ati ifojusun rẹ fun idije si ipo gomina ni ọdun 2022.

Image copyright Facebook/Ademola Adeleke

Laipe yii ni sẹnetọ Adeleke kuna ni ile ẹjọ to gaju, lẹyin ti ile ẹjọ ni Oyetola lo jawe olubori ninu idibo si ipo gomina to waye ni ọdun 2018 ni ipinlẹ Osun.