Yinka Ayefele di bàbá ìbẹta

Yinka Ayefele Image copyright Yinka ayefele
Àkọlé àwòrán Iroyin ti a ri gbọ sọ pe gbajugbaja olorin naa ṣalaye fawọn oṣiṣẹ rẹ loni

Gbajugbaja olorin ni to tun jẹ oludaleeṣẹ redio silẹ, Yinka Ayefẹlẹ ti di baba ibẹta bayii.

Gẹgẹ bii iroyin ti o n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo, loni ni Yinka Ayefẹlẹ tu iroyin ayọ yii fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio rẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe laipẹ yi ni iroyin kan ti kọkọ jade pe iyawo onkọrin yii bimọ ṣugbọn ti oun pẹlu tete bọ si igboro lati salaye pe iyawo oun ko tii bimọẸ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, n kò bí ìbẹta - Yinka Ayefẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionThomas Crowther ṣe àtúpalẹ̀ ìwádìí yìí ni orilẹ-ede àádọrin ní àgbáyé

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ rẹ to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe ori oju opo ikansiraẹni Whatsapp to jẹ tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Redio rẹ lo ti tu iroyin ayọ naa fun awọn oṣiṣẹ rẹ loni.

Image copyright yinka ayefele

Bakan naa ni Yinka Ayefẹlẹ funrarẹ ti kede rẹ loju opo Facebook rẹ pe orin ijo ọmọ mo ji fowurọ mi jo ti oun kọ ninu awo orin oun kan lọjọ ọjọsi ti di otitọ bayii.