Idowu Olakunrin: Kò sí ẹni tó lé è dí àlàfo tí Funke fi sílẹ̀

Olufunke Olakunri Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọkọ olóògbé Olufunke Olakunri bú sí ẹkún lásìkò tó ń se ìdárò ìyàwó rẹ̀ tí àwọn agbébọn pa ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Arakunrin Idowu Ọlakunri to jẹ baale ile oloogbe Olufunke Olakunri ti ni wura oniyẹbiye ni iyawo oun ti awọn agbebọn pa.

Olakunri sọ eyi lasiko isin ikẹyin fun oloogbe naa, ni ibi ti arakunrin naa ti sun ẹkun kikoro lasiko to n se idaro iyawo rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn ọdọ Ondo fẹ̀họ́nù hàn lórí ìṣekúpani Funke Olakunrin

O fikun un wi pe ko si ẹni to le e di alafo ati ọgbẹ ọkan ti iku iyawo oun da silẹ fun oun ati awọn ọmọ pẹlu ẹbi ati ara.

Ọkọ oloogbe naa ṣe ajuwe Funkẹ gẹgẹ bi obinrin to mọ itọju ẹbi ati ara, ti o si ni ifọkansin lati se aseyori lori ohun gbogbo to ba fi ọkan si lati ṣe.

Ọjọ Kejila, Osu Keje, ọdun 2019 ni awọn agbebọn da ibọn bo arabinrin naa ni ọna Benin/Ore, eleyii ti o si jasi iku Olufunke Olakunri.