Shiite protest: Ọ̀gà ọlọ́pàá pàṣẹ́ kí ètò ààbò le si kárakára

SHIA
Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ ẹ̀mí ló sọnù sí ìkọlù láàrín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ẹlẹ́sìn Shia tí wọ́n ń pè fún ìtúsílẹ̀ adarí wọn, EL-Zakzaky.

Ọga Ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ti fun awọn eleto aabo ni aṣẹ lati ri pe eto aabo gbona jainjain si i ni awọn ipinlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria ati ilu Abuja.

Mohammed Adamu fi ọrọ naa lede lataari ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa ati awọn ẹlẹsin Shia, eleyii ti o mu ọpọ ẹmi lọ.

Adamu fi da awọn eniyan loju wi pe awọn yoo ṣiṣẹ karakara lati ri pe eto aabo to muna doko wa fun awọn olugbe Naijiria.

Awọn ẹlẹsin Shia naa n beere fun itusilẹ adari wọn, El-Zakzakky to ti wa ni atimọle ijọba lati ọdun 2015 lori ẹsun pe wọn n da ilu ru.

Oga agba ọlọpaa fi awọn eniyan Naijiria lọkan balẹ pe awọn agbofinro n ṣiṣẹ bi o ti yẹ lati ri si aabo ẹmi ati dukia awọn ara ilu.

Àkọlé fídíò,

Human Rights day: Aṣíwájú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní Àìbọ̀wọ̀ fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ń fa wàhálà ètò àbò

Adamu gba awọn eniyan ni imọran lati yẹra fun awọn iroyin ati ikede ti o jinna si ootọ ti o n ko ipaya ba awọn eniyan.

Àkọlé fídíò,

Shiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù

Oga agba awọn ọlọpaa ni ko si ẹni to n sọ pe ki awọn olujọsin Shiite ma sọ ohun ti wọn n fẹ lọwọ ijọba ṣugbọn wọn ko gbọdọ fa ijọngbọn.

Àkọlé fídíò,

Ẹ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Bakan naa ni ọga ọlọpaa naa kilọ fun awọn ara ilu lati ye e gbe iroyin ofege, ti o le da ibaṣepọ ati alaafia orilẹ-ede Naijiria jẹ.

Ni Ọjọ Ẹti ni iroyin kan n tan kaakiri ori ẹrọ ayelujara wi pe ki awọn eniyan ko sora lati rin ni ilu Abuja, Lagos, Kaduna, Kano, Katsina, Gombe ati Bauchi, nitori iwọde awọn ẹlẹsin Shia.

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó