Gomina Makinde:Osù tó ń bọ̀ la ó gbé ètò ààbò ilẹ̀ Yoruba jáde!

Ìwò-Òòrùn Naijiria Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Gomina Makinde:Osù tó ń bọ̀ la ó gbé ètò ààbò ilẹ̀ Yoruba jáde!

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti ni awọn gomina ni ẹkun Iwo-oorun guusu Naijiria ti mura lati se ifilọlẹ eto aabo to gbooro ni osu to n bọ.

Makinde sọ ọrọ yii ni Ọjọ Isinmi nibi ayẹyẹ iranti iya rẹ to doloogbe ni ile ijọsin Saint Paul's Anglican church, Yemetu, Ibadan.

O ni ki oun to lo ọgọrun ọjọ ni ijọba ipinlẹ naa ni awọn yoo bẹrẹ eto aabo to munadoko kaakiri ipinlẹ naa.

Gomina ipinlẹ Ọyọ naa ni awọn gomina ni ẹkun naa n se ipade igba de igba lati wa ọna abayọ si eto aabo to dẹnu kọlẹ, eleyii ti o ti jasi iku fun awọn eniyan kan ni agbeegbe naa.

Image copyright Google

Laipe yii ni gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, Gomina ipinlẹ Ọyo, Seyi Makinde, Gomina ipinlẹ Osun,Adegboyega Oyetola, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi,Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati Gomina ipinlẹ Ogun, dapo Abiodun parapọ se ipade ni Iwo-Oorun Naijiria lori ọna abayọ si ipenija eto aabo to mẹhẹ ni ilẹ Yoruba.