Nigeria Army: Ọmọ ológun gún awakọ̀ lọ́bẹ pa

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kini awakọ le ṣe fún ọmọ ológun to fi rí ikú he?

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ipínlẹ̀ Edo tí mú ọmọ ologun, kọpora Mose Oguche tí wọ́n fẹ̀sùn kan pe ó gun awakọ pa ní ìlú Okenne ni ipínlẹ̀ Kogi.

Gẹ́gẹ́ bi ile iṣẹ́ ọlọpàá ṣe fi idi rẹ̀ múlẹ̀, ọlọpàá mú Oguche pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ará ìlú lẹ́yìn ti àwọn ọmọ ológun tún fẹ gba akẹgbẹ́ wọ́n kúrò ni àhámọ ọlọpàá.

Kọ́misọnà ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Edo, Muhammed DanMallam tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

O sàlàyé pé àwọn yárá fi afurasí ọ̀hun sọwọ́ sí olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní Benin nígbà ti àwọ́n gbọ́ pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ fẹ́ wá fípa gbà á kúrò ni agọ́ ọlọpàá.

Bakan náà ni DanMallam fi ọkàn ará ìlú balẹ̀ pé ìdájọ ododo ní yóò wáye lori ọ̀rọ̀ náà nítori pé kò si ẹnikẹ́ni tó kọjá òfin.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ agbẹnusọ àwọn ọlógun ti ẹka 4 Brigdade Army, Cap Maidawa Mohammed sọ pé ìwà ti ọmọ ogun Oguche hù yìí kò ba òfin àti àlàsílẹ̀ iṣẹ́ àwọn mú.

O ni nítorí pé àwọn kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ẹmi rara ninu iṣẹ ologun.

Maidawa ní bi wọ́n ṣe fi ẹsùn kan, ilé iṣẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe ìwádìí tó péye láti fi ìdí òdodo múlẹ̀ tí ìdájọ òdodo yóò si tẹ̀lé ìwádìí náà.

Àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sojú wọ́n ṣàlàyé pé ẹni tí wọ́n gún pa yìí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ Ogbimi àti atún ọkọ̀ ṣe kan lọ gbé ọkọ kan ti ó dẹnukọlẹ̀ fún àtúnṣe.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọlọ́pàá fi panpẹ ọba mú ọmọṣẹ̀ ológun

Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nígbà ti ọkọ̀ ti wọ́n fi maa n fa ọkọ to bàjẹ̀ ti olóògbé n wà lọ fí ara họ ọkọ ayọkẹlẹ Nissan Primera pẹlu Nọmba Abuja KWL 811 AP to jé ti ọmọ ológun yìí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015