Security Summit: Ìlànà òfin ní ó yẹ kí Naijiria tọ̀ kìí ṣe ipàdé àbòsí- Odumakin

Image copyright AFfenifere
Àkọlé àwòrán Security Summit: Ìlànà òfin ní ó yẹ kí Nigeria tọ̀ kìí ṣe ipàdé àbòsí- Odumakin

Láìpẹ̀ yìí ní ọ̀gá ológun Nàìjíríà nígbà kan ri, Abdulsalami Abubakar pé fun àpérò lóri ètò àbò tí yóò wáye ní ìlú Minna tíí se olú ìlú ìpínlẹ̀ Niger.

Bákan náà ni ọgágun náwọ́ ìwé ìpè apero yii sí ẹgbẹ́ Afẹnifere tí ó ń soju fún ẹ̀yà Yorùbá ìhà Guusu - ìwọ̀-òòrun Nàìjíríà.

Sùgbọ́n lánàá òde yìí ni ẹgbẹ́ àfẹnifẹre fi àtẹ̀jáde kan síta pé àwọ̀n kò ni péjú níbi ìpàdé àperò ọhun.

Apero naa ni wọn ni yóò maa wá ojúútu si òmi ètò ààbò to ti ń dàrú ni ìhà Guusu - ìwọ̀-òòrun Nàìjíríà láti oṣù díẹ sẹ́yìn.

Àwọn adarí ìhà gúúsù, àti àrin gbùngbùn Nàìjíríà to fi mọ Pa Adebanjo tó jẹ adarí ẹgbẹ́ Afẹnifẹre kọọ nínú àtẹjisẹ kan pé àwọn ò ni kópa nínú àpérò náà.

Eyi to yẹ kí ó wáyé láàrin ọjọ Ajé, ọjọ́ kọkàndínlọgbọ̀n sí ọgbọ̀n ọjọ́, ní ìlú Minna

Lára ìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti kópa ní pé wọ́n pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Miyetti Allah síbi àpérò náà ati pe àwọn kò si ṣetan láti jọ jòkó pọ̀ fún àpérò pẹlu darandaran.

Kíní ó yẹ ki ìjọba ṣe dípò ìpàdé yìí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwa ò le jọ jókòó pọ̀ ṣèpàdé pèlú ẹgbẹ́ àwọn darandaran

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sàlàyé pé àrífin àti àìkanikún ní irú ìpàdé bẹẹ.

O ni nígbà ti àwọn ọmọ Niger-Delta ń ji ènìyàn gbé ní ìlú Ikorodu ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìpàdé tó wáye to sì fi òpin sí gbogbo rògbòdìyàn lásìkò náà wáyé láarin àgbàagba Yòrùbá àti ti Niger Delta.

O ni nibẹ ni wọn ti ran wọn lọ kìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọ́n láti lọ so àgbéjẹ mọ́wọ́.

Yinka Odumakin ni bíí ìfira-ẹni-wọ́lẹ̀ ni ti àwọn ba péju sibi ìpàdé náà ati pe awọn ẹgbẹ agba iran bii Ohaneze naa ti ni awọn ko ni kopa.