Samuel Okwaraji: Kíni ẹ̀yín mọ nípa akọni yìí?

Samuel Image copyright NFF
Àkọlé àwòrán Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà

O ní ló pé ọgbọ̀n ọdún gbáko ti akọni agbábọ́ọ̀lù, olùfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kú lásìkò tó ń ṣe ojúṣe rẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

A bí Samuel Okwaraji ní ọdún 1964 sí ìdílé ọgbẹ́ni David Okwaraji àti Janet Okwaraji, ó sì lọ ilé ìwé WTC practicing ní Enugu fún iwé alákọbẹ̀rẹ̀ àti Ezeachi fún grammer, bákan náà ló lọ sí Federal Government College ni Orlu ni ìpínlẹ̀ Imo.

Ó lọ sí fasiti ni Rome ni orilẹ̀-èdè Italy níbi to ti gba oye nínú ìmọ̀ òfin bàkàn náà lo tún gba oye ipele kejì sùgbọ́n kò lo èyí lẹ́yìn to pari ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Lásìkò tó ń ka iwé fún ìmọ̀ ofin oní pele kejì ló bẹ̀rẹ̀ si ni gbá bọ́ọ̀lù fún NK Dinamo Zagreb, VfB Stuttgart àti SSV Ulm 1846 níbi to ti fọmọ yọ ninu iṣẹ́ to yàn láàyò.

Ọdún 1988 ni Samuel Okwaraji darapọ̀ mọ́ Green Eagles èyí to di Super Eagles lónìí, lásìkò African Nations Cup, o gbá bọ́ọ̀lù lásìkò yìí náà ní Morocco ti o sì gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n láàrin isẹjú kan níbi ifsẹwọnsẹ pẹ̀lú Indomitable Lions ti Cameroon.

Samuel Okwaraji gbá bọ́ọ̀lù ní Summer Olympics to wáye ni Seoul, South Korea, pẹ̀lú awọn bíi Samson Siasia, Rashidi Yekeni, Bright Omokaro, Wole Odegbami, Christain Obi, Jude Agada àti Henry Nwosu.

Sùgbọ̀n ọ̀fọ̀ nla ṣe Nàìjíríà ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹjọ, ọdún 1989 lásìkò ti Okwaraji pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Ó kú ikú àìtọ́jọ́ lóri pápá níbi to ti n gba bọ́ọ̀lù níwáju àwọn èrò ìwòràn tó lé ni ọgọ́rùn lọ́nà ogun ní pápá ìṣeré National Stadium, ní ìlú Eko. Ibẹ́ lo ti subú lulẹ̀ tó sì kú.

Ìṣẹ́jú mẹ́tàlá ló kù ki ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ parí láàrín Nigeria ati Angola ní National Stadium ìpínlẹ̀ Eko èyí ti yóò mú wọọn pegede fún ife ẹ̀yẹ FIFA.

Láti ọdún yìí ni Nigeria, ọlọ́dani àti àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ǹkan máni gbàgbé láti ránti akọni to ti papodà yìí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015

Babajide Raji Fashola tó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko nígbà kan rí, mọ ere Okwaraji si ìwáju National Stadium láti maa ṣe ìránti rẹ̀ ńtori pé pápá iṣèré yìí náà ló ti kú.

Image copyright Lagos state
Àkọlé àwòrán Samuel Okwaraji: Kíni ẹ̀yín mọ nípa akọni yìí?

Bí oní ṣe wá jẹ́ ọgbọ̀n ọdún gééré gé ti Samuel Okwaraji papo dà ajọ NFF náà ń selédè lẹ́yin rẹ̀.

Image copyright Nff
Àkọlé àwòrán Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti ń ṣelédè lẹ́yìn Okwaraji bí wọ́n ṣe n ṣe ayájọ́ ọgbọ̀n ọdún to ti papo dà, sùgbọ́n wọ́n fi ẹdùn ọ̀kan wọ́n hàn pé, NFF àti ìjọba ko ti ṣe tó:

Àkọlé àwòrán Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà