EL-Zakzaky: DSS ti fi El-zakzaky sílẹ̀ láti lọ sí India fún ìwòsàn

El-Zakzaky Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Agbẹjọ́rọ̀ fún El-Zakzaky, Femi Falana ní lóòtọ́ ni Àjọ DSS tí fún adarí IMN ní Naijiria náà láàyè láti lọ gba ìwòsàn.

Adari Ẹgbẹ Musulumi Shia, Sheikh Ibraheem El-Zakzaky ati iyawo rẹ, Zeena ti setan lati bẹrẹ irinajo lọ si India, lẹyin ọdun mẹta ti wọn ti wa ni atimọle Ajọ eleto aabo, DSS.

Agbẹjọrọ fun El-Zakzaky, Femi Falana lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba

Falana ni asalẹ oni ni awọn mejeeji yoo gbera kuro ni ilu Abuja lọ si India lati lọ gba itọju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKílò fa èdè àìyedè láàrin ìjọba àti àwọn ọmọ lẹ́yìn El-Zakzaky?

O fikun wi pe awọn ko damu ara awọn lati mu asẹ ijọba ipinlẹ Kaduna se lori awọn ilakalẹ ti wọn fi le le lori irinajo El-Zakzaky lọ si India, nitori Ajọ DSS ti ni awọn yoo mu asẹ ile-ẹjọ sẹ.

Bakan naa lo fi kun wi pe ohun ko ni ẹjọ kan kan ba ijọba ipinlẹ Kaduna ro.

Agbẹjọ́rọ̀ fún Elzakzaky, Femi Falana ní ọdún 2015 tí wọn ti wà látìmọ́lé ni wọ́n kò tíì ní ìtọ́jú tó péye.