Osun Cabinet: Kí ló fàá tí gómìna ìpínlẹ̀ osun kò fi yan kọmíṣọ́nà lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn án?

Gboyega Oyetọla Image copyright @GboyegaOyetola
Àkọlé àwòrán Awọn kọmiṣọna labẹ iṣejọba ana lo n dele lawọn ileeṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ọṣun.

Wọn ni bi a ba de idi iṣẹ ṣiṣe laa ṣe e, amọṣa awọn kan ti n kọminu lori bi awọn gomina kan lorilẹede Naijiria, paapaa julọ lagbegbe iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, ṣe n fi ọrọ agbekalẹ igbimọ iṣejọba wọn falẹ.

Lara awọn gomina ti aje ọrọ yii ṣi mọ lori ni gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla. Oun pẹlu si ti dide lati gbeja ara rẹ pe, o ni idi ti ọrọ fi ri bẹẹ fun oun lẹyin oṣu mẹsan ti oun gun ori aleefa.

Gomina Oyetọla ni oun ṣi n wa awọn eeyan to ni iran kan naa pẹlu oun lori iṣejọba ipinlẹ naa ni.

O ṣalaye ọrọ yii lasiko ti o fi n ba awọn oniroyin sọrọ ni ile rẹ to wa nilu Iragbiji tii ṣe ilu rẹ.

Gomina Oyetọla ni, awọn ti yoo lee mu ki ilepa ijọba oun atawọn ileri ti oun ṣe faraalu o tete wa si imuṣẹ, loun n wa ati pe laipẹ lawọn eeyan naa yoo ṣarajọ.

Lẹnu lọwọ lọwọ yii, ni iroyin gbode pe awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ naa atawọn ọmọ ẹgbẹ naa kan, ti n gbe ina woju ara wọn lori fifi orukọ awọn ti yoo jẹ kọmiṣọna ranṣẹ si gomina naa.

Gomina Oyetọla ni oun ti " ranṣẹ si awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣawari awọn ti yoo kopa ninu igbimọ iṣejọba oun.

Idi ti a fi fi ọrọ naa kọ ẹgbẹ lọrun ni lati rii pe gbogbo eeyan lo lọwọ si yiyan awọn ti yoo jẹ kọmiṣọna."

O ni oun fẹ ki ilana yiyan kọmiṣọna si ijọba oun jẹ eyi ti yoo ko akoyawọ lo tun faa, ti igbesẹ naa fi n falẹ.