Police Killing: Ọlọpàá mẹ́rìn to pa afurasí dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn

CP Zubairu Muaz Image copyright Twitter/Nigeria Police Force
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko gbaṣẹ lọwọ ọlọpaa mẹrin

Awọn agbofinro tó yinbọn pa awọn afurasi meji ti dero ẹwọn bayii.

Ilé iṣẹ́ ọlọpaa ti fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn ọlọpàá mẹ́rìn ti wọ́n pa àwọn afurasí mẹ́jì kan, èyí ti fọnran rẹ̀ ń jà ràìnràìn lórí ẹ̀rọ ayélujára ti pàdánù iṣẹ́ wọn bayii.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Bala Elkana ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọròyìn pé awọn ọlọ́pàá náà ti fojú ba iléẹjọ́ l'Ọjọ́bọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlapàá ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá náà jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Image copyright Policeng
Àkọlé àwòrán Ọwọ́ ti tẹ ọlọpàá mẹ́rìn to pa afunrasí

Elkana fi kun un pé àwọn ti mú àwọn ọlọpàá náà si àtìmọ́lé lẹ́yìn ti fọ́nran náà lu sí ìgboro.

"Bí àwọn ará ìlú ṣe pé àkíyèsì wa sí bi àwọn òsìsẹ wá ṣe yìbọn pa àwọn afúrasi méjì kan ti kò ní ǹkan ìjà lọ́wọ́, èyí lòdì sí ìlànà iṣẹ́ wa kò sì bá òfin mu rárá.

Ati pé ìlànà náà ki ṣe bi ọlọpàá ṣe ń ṣe àwọn afúrasi to ba wà ní àyíká wọ́n "

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJoe Igbokwe kò yẹ́ fún ipò ti wọ́n fún nípìnlẹ̀ Eko - Babatunde Gbadamosi

Awọn ọlọpàá náà ní Insp. Fabiyi Omomayara, Sgt. Olaniyi Solomon, Sgt. Solomon Sunday àti Cpl Aliyu Mukaila tó wọ́n so mọ agbegbe Iba.

Ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹjọ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni déedé ààgọ mẹ́ta ọ̀sán, nígbà ti ilé iṣẹ ọlọpàá gba ipe láti ọdọ Anugu Valentine kan, pé àwọn ọkunrin méji kan dá oun lọna lóri ọkàda ti wọn si gba Iphone oun ti owó rẹ̀ din díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹẹdẹ́gẹ̀tá náìra ni àgbègbè Iba.

Eyi ló mu ki wọ́n ràn ọlọpàá lọ sí ibẹ̀, méjì nínú àwọn afurasi náà sálọ nígbà ti wọ́n mú méjì, agbẹnusọ náà ni wọ́n gba ibọn ìbílẹ̀ méjì àti ọtá ibọn mẹ́fà gbà lọ́wọ́ wọ́n.

Ẹwẹ̀, kọmísọna ọlọpàá, Zubairu Muazu ti pá a láṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwàdìí tó péye.