Ministerial Position: Gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ tí ààrẹ yàn mínísítà fún lo ti wà tẹ́lẹ̀ - Garba Shehu

Aworan
Àkọlé àwòrán Ministerial Position: Gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ tí ààrẹ yàn mínísítà fún lo ti wà tẹ́lẹ̀ - Garba Shehu

Lánà òdé yìí (21-08-2019) ní ààrẹ Muhammadu Buhari kéde àwọn ilé iṣẹ́ márun un tuntun míràn nígbà tó yan àwọn mínísítà.

Awon ipò náà ni Minisita fun eto ọrọ araalu, ajalu ati idagbasoke awujọ, Minisita fun eto amuṣagbara, Minisita fun igboke-gbodo ọkọ ofurufu, Minisita fun akanṣe iṣẹ ati ọrọ okeere, Minisita fun ọrọ awọn ọlọpaa.

Ilé iṣẹ́ tó ń ri sí ìrìn ojú furufu, ti wà lára iléṣẹ́ ìrìnnà tẹ́lẹ̀, èyí ti Hadi Sirika ń sojú lásìkò tó tó jẹ mínísítà abẹ́lé fún ìrìnnà ojú ofúrúfu.

Ilé iṣẹ́ amuṣagbara tí wà lára ilé iṣẹ́ tó ń ri si ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àti ilé igbé tí Babatunde Fashola jẹ mínísita rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ Naijiria ti sọ̀rọ̀ síta lórí ohun ti wọ́n ń retí lọ́dọ̀ minista tuntun

Ààrẹ Muhammadu Buhari tún fi ìdí èyí múlẹ̀ lásikò tó ń yàn wọ́n sípò nílé ìjọba pé àwọn ti wọ́n yà sọ́tọ̀ yìí jẹ́ ọ̀nà láti fẹ́ ètò ìjọba lóju síi.

Ati pe eyi ni lójùnà àti mú ìjọba awa ara wa gbẹ̀rú síi.

Àwọn ilé iṣẹ́ tó jọ bi ẹni pe kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta ní Minisita fun eto ọrọ araalu, ajalu ati idagbasoke awujọ.

Eyi ni Sadiya Umar Faruk lati (Zamfara) a maa moju to ati ilé iṣẹ́ akanṣe iṣẹ ati ọrọ okeere, ti George Akume láti (Benue) ń soju fún.

Bakan náà ní ìlé iṣẹ́ ọlọpàá tí dá dúro bayìí kuro labẹ ileṣẹ ijọba apapọ ti ọrọ abẹle ti Mohammed Maigari Dangadi (Sokoto) ń soju.

Njẹ ìjọba yóò dá àwọn ilé iṣẹ́ tuntun yii silẹ̀ ni?

Ìbéèrè yìí ló mú ki BBC ṣe ìwádìí ìgbéṣẹ̀ tí ìjọba fẹ́ gbé tí a si pé olubadamọràn pàtàkì fún ààrẹ Buhari lóri ìfìtónilétí Garba Shehu.

Garba Sheu, sàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tí tọ́kọ́taya ba túka ni, ó fí kún-un pé gbogbo àwọn ipin yìí ló ti wà tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì ni àwọn àkọ̀wé ilé iṣẹ́, sùgbọn ni ọdún 2015 ní ìjọba dà wọ́n pọ̀ tó sì tún pín wọ́n bàyíì

Agbẹnúsọ ìjọba fi kún un pé ní bayìí gbogbo wọ́n yóò pada si ibi tí wọ́n ti wá.