Afẹ́nifẹ́re kò lọ́wọ́ sí Asíwájú Yoruba tuntun tí wọ́n yàn- Odumakin
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Afẹ́nifẹ́re kìí ṣe asọju ọmọ Yorùba, ẹgbẹ́ lásàn ní wọn

Ọ̀rọ̀ asíwájú ilẹ̀ Yorùbá túntún ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lánàá òdé yìí túbọ̀ n dá èdè aìyede sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Yorùbá.

Bí ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re ṣé ń sọ pé àwọn ò mọ̀ nípa ìyànsípò náà ní asojú àwọn tó gbé ètò náà kalẹ̀ ní tí ẹgb afẹnifere o ba mọ ǹkan to yẹ ki wọ́n ṣe àwọn míràn yòó ṣe.

Victor Taiwo to jẹ́ asojú ẹgbẹ́ ọmọ òòdua Redemption Alliance sàlàyé pé ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re kìí ṣe asoju ọmọ Yoruba náà ni Odumakin fi kún pé ẹgbẹ́ tó ṣe ètò náà kó to ẹru yoruba gbé.