Nigeria Visa: Ìjọba Naijiria ti mú ẹ̀dínkù bá owó ìwé ìrìnnà fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Amerika láti wá sí Naijiria

USA-NIGERIA Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Láìpẹ̀ yìí ni ìjọba orílẹ̀-ède Amerika polongo àfikún owó ìrìnna fún àwọn ọmọ Naijiria tí ó bá fẹ́ wá sí Amerika.

Ijọba orilẹ-ede Amerika ti kesi ijọba Naijiria pe awọn ko i ti i ri iwe lati ọdọ ijọba wi pe ẹdikun ti ba owo iwe irinna fun awọn ọmọ ilẹ Amerika to fẹ wa si orilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede, ile-iṣẹ ilẹ Amerika ni Naijiria ni o di igba ti wọn ba fi iwe ranṣẹ si awọn ni awọn yoo yọ afikun owo iwe irinna ti awọn fi le owo fun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ wa si ilẹ Amerika.

Láìpẹ̀ yìí ni ìjọba orílẹ̀-ède Amerika polongo àfikún owó ìrìnna fún àwọn ọmọ Naijiria tí ó bá fẹ́ wá sí Amerika.

Bakan naa ni ijọba Naijiria wa gbe e jade pe awọn ti mu ẹdinku ba owo irinna fun awọn ọmọ ilẹ Amerika naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDomestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run

Ijọba tí júwọlẹ̀ fún Amẹrika lóri iwé ìrìna!

Ijọba orilẹede Naijiria ti buwọlu ayipada si owo ti awọn ọmọ orilẹede Amerika to ba fẹ wa si Naijiria yoo ma san gẹgẹ bi owo Iwe Irinna(Visa).

Nibayii, wọn yoo ma a san aadọjọ owo ilẹ okeere ($150), dipo ọgọsan dọla ($180) ti wọn n san tẹlẹ.

Igbesẹ yii ko sẹyin bii ijọba orilẹ-ede Amerika se polongo afikun owo irinna fun awọn ọmọ Naijiria ti o ba fẹ wa si Amerika nitori owo goboi ni awọn ọmọ ilẹ Amerika n san lati wọ Naijiria.

Minisita fun ọrọ abẹle lorilẹ-ede Naijiria, Ogbeni Rauf Aregbesola sọ wi pe lẹyin ajoyepo pẹlu igbimọ ni awọn gbe igbesẹ lati mu ẹdinku ba iye owo iwe irinna naa.

Bakan naa lo fikun un wi pe awọn ti pasẹ fun Ọga Agba Ile -Isẹ to n risi irinna lorilẹ-ede Naijiria (NIS), Muhammad Babandede wi pe ọjọbọ, ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu yii ni asẹ ẹdinku naa yoo bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBadagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ