Election Tribunal: Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ tó da ẹjọ́ Atiku nù!

Election Tribunal Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ti ní àwọn ń gba Ilé-ẹjọ́ tó gajùlọ lọ, lẹ́yìn tí ilé-ẹjọ́ dá ẹjọ́ tí wọ́n pè mọ́ Ààrẹ Buhari nù.

Idajọ yẹn dara; idajọ naa ku diẹ kaa to ni ọrọ awọn eniyan Naijiria lasiko yii.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n lọ lori idajọ ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun eto idibo, lẹyin ti ile ẹjọ ni Aarẹ Buhari lo wọle ninu idibo to kọja nitori oun lo ni ibo to pọ julọ.

Ẹgbẹ oselu PDP ati oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ naa, Atiku Abubakar gbe Aarẹ Buhari lọ si ile ẹjọ wi pe ko ni ẹtọ ni abẹ ofin lati du ipo ni orilẹ-ede Naijiria nitori ko ni sabuke (School-leaving Certificate), ati wi pe ọpọlọpọ magomago lo sẹlẹ ninu idibo eyi.

Ẹgbẹ oselu PDP n wa ki ile ẹjo da idibo to gbe Aarẹ Buhari wọle nu, amọ adajọ ni gbogbo ẹjọ ti PDP pe mọ Aarẹ Buhari ni ko lẹsẹ n lẹ.

Wọn ni pe Aarẹ Buhari lo wọle idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.

Lara awọn ololufẹ ẹgbẹ oselu APC to fi ero wọn lede ni oju opo Twitter ni wọn gboriyin fun idajọ naa gẹgẹ bi eyi to lamilaaka.

Wọn ni idajọ naa ko si faaye silẹ fun iwa ibajẹ ni ẹka eto idajọ lorilẹ-ede Naijiria, nitori wọn se idajọ naa lẹsẹẹsẹ.

Amọ awọn olulufẹ ẹgbẹ oselu PDP ti ko faramọ idajo naa bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu eto idajọ lorilẹ-ede Naijiria.

Wọn ni Aarẹ Buhari ati awọn adajọ naa se ifẹ inu wọn, eleyii ti wọn si lo tako ohun ti awọn ọmọ Naijiria fẹ.

Ni bayii, ẹgbẹ oselu PDP ti ni awọn n gba ile-ẹjọ to ga julọ lọ, nitori o da awọn loju wi pe ẹgbẹ oselu PDP lo wọle ninu idibo si ipo aarẹ ti ọdun 2019.