FUOYE: àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ kí Gómìnà Fayemi àti ìyàwó rẹ̀ tọrọ ìdáríjí

Awọn akẹkọ Fasiti ijọba apapọ ni ilu Ọyẹ Image copyright @vasitidotcom
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ NANS ní kí Gómìnà Kayọde Fayemi àti ìyàwó rẹ̀ tọrọ ìdáríjí lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ́ Fásitì Ọyẹ́ lórí ìkólù tí àjọ ọlọ́pàá ṣe sí àwọn akẹ́kọ́ náà lọ́sẹ̀ tókọjá.

Ẹgbẹ akẹkọ lorilẹede Naijiria, NANS, ti sọ pe ki Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ati iyawo rẹ, Bisi Fayemi tọrọ aforiji lọwọ awọn akẹkọọ Faisiti to wa ni Ọye Ekiti.

Eyi ko sẹyin bii ẹmi awọn akẹkọọ to sọnu lẹyin ikọlu ti awọn ọlọpaa ṣe si awọn akẹkọ naa, nibi iwọde kan, lọsẹ to kọja.

Alukoro apapọ fun ẹgbẹ naa, Azeez Adeyemi lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu kan BBC Yoruba.

Adeyemi ni, ọkan lara awọn akẹkọọ to ṣeṣe nigba ti ajọ ọlọpaa ṣe ikọlu si wọn nibi iwọde ọhun.

‘Azeez Elijah ti n gba iwosan lọwọ, sugbọn ko lee gbe apa ati ẹsẹ rẹ mọ.’

‘Elijah to wa ni ile iwosan yii ni ẹni to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni Fasiti ọhun. O ṣeṣe lẹyin ti awọn ọlọpaa yin tajutaju si awọn akẹkọọ ọhun nibi ifẹhonuhan naa.’

Adeyẹmi sọ siwaju si pe, NANS yoo gbe idile gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ṣepe, bi nnkankan ba ṣẹlẹ si awọn akẹkọ to ṣeṣe nibi iwọde naa.

O ni, to ba jẹ bi awọn ti wọn ṣe ijọba ni igba ti Fayemi tabi iyawo rẹ wa ni kekere ṣe fi ọwọ ọla gba awọn akẹkọọ loju ni yii, oṣeṣe ki iru eeyan bi Fayẹmi ma de ipo goimina.

Beẹ lo pari ọrọ rẹ pe, ẹgbẹ NANS ti yọju si ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, lori iwadi rogbodiyan ọhun lọna lati mọ okodoro bi iṣu ṣe ku, ti ọbe si buu.