Champions League: Àwọn ohun tóyẹ kí ẹ mọ̀ nípa ti sáà yíí

Manchester City, Cristiano Ronaldo, Lionel Messi, Ajax, RB Leipzig ati Liverpool Image copyright Getty Images

Njẹ o ṣeeṣe ki ẹgbe agabọọlu Ilẹ Gẹẹsi jawe olubori ninu idije UEFA Champions League ti saa yii bi? Awọn ti La Liga nkọ? Bawo ni igberadi ikọ Ajax?

Ninu idije Champions League ti yoo bẹrẹ loni yii ni ẹgbẹ agbabọọlu jankọ jankọ yoo ti gbena woju ara wọn.

Aṣalẹ oni ni Liverpool yoo rinrin ajo lọ si Napoli, lati lọ koju ikọ ọhun, ti Chelsea yoo si gba ikọ Valencia lalejo.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni ikọ Dotmund yoo gba ikọ Barcelona lalejo loni.

Lọjọru ni ikọ Juventus yoo lọ waako pẹlu Atletico Madrid, ti Paris St-Germain yoo si sare kadara pẹlu Real Madrid.

Meji lara awọn mẹta ninu ẹgbẹ agbabọọlu ti awọn onwoye bọọlu alafẹsẹgba n ro pe yoo gba ife ẹyẹ ti saa ni ikọ Liverpool ati ikọ Manchester City, to jawe olubori ninu idije Premier League.

Image copyright Getty Images

Ikọ Liverpool ni afojusun lati ṣe oun tẹnikan o ṣe ri lati igba ti idije naa ti pawọda si Champions League lọdun 1992, eyi ni lati gba ife idije naa lẹkan sii.

Awọn kan tun fi oju mii wo ikọ Manchester City bi ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹye naa fun igba akọkọ lẹyin ti Joao Cancelo ti dara pọ mọ ikọ ọhun, ti Kevin de Bruyne si ti gbaradi fun ere ori papa lẹyin ti ara ti mokun sii.

Ikọ Tottenham naa ko ni gbéyin, ni bi ikọ naa ti kẹkọọ lẹyin ti ikọ Liverpool fẹyin wọn janlẹ ni saa to kọja. Bi o tilẹ jẹ pe ikọ naa ko ra atamatase kankan ti Harry Kane si ti sese, sugbọn agbo to fẹyin rin, agbara lo lọ muwa.

Frank Lampard ni yoo jẹ akọnimọọgba fun igba akọkọ nigba ti o yoo ko awọn ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea sọdi wa si idije naa. Lampard to gba ife ẹyẹ European Champions League lọdun 2012 lo rọpo Maurizio Sarri lọdun yii gẹgẹ bi olukọni funn Chelsea.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionUnicycle School: Olùdarí ibùdó ìkẹ́kọ̀ kẹ̀kẹ́ alájọwà ń fẹ́ ìrànwọ́ ìjọba