Ore-Lagos Accident: Ìjàmbá ọkọ́ gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀, èèyàn méje farapa

Ajọ FRSC Image copyright @OtutuNg

Awọn eeyan kan ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Ọre si Eko, ni ijọba ibilẹ Odigbo, ti eeyan meje si farapa.

Ọkọ akero Toyota Hiace to ni nọmba AKL 930 YYY ati ọkọ ajagbe MAN, to ni nọmba FGB 737 XA ni wọn kọlu ara wọn.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn oniroyin pe "ijamba naa lo ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Ọrẹ, ni agbegbe Adekunle, ọkọ ajagbe kan to n sare asapajude lo kọlu ọkọ akero to n bọ lati ọna Eko, eyi to yọri si iku awọn eeyan ti ọpọlọpọ si farapa."

Ijamba naa lo da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ loju popo naa, ki ajọ awọn ẹṣọ oju popo, FRSC to wa ko awọn to gbẹmi mi, ati awọn to ṣeṣe nibi iṣẹlẹ naa lọ si ile iwosan.

Olori awọn oṣiṣẹ FRSC ni agbegbe naa, Olusegun Ogungbemide ni "Awọn mẹtala lo wa ninu ijamba naa ti awón kan si ti jẹ Ọlọrun nipe."

O salaye siwaju sii pe, ere asapajude lo fa ijamba ọhun.