Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Èrò àwọn olólùfẹ̀ Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin lórí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín wọn

Toyin Lizzy Anjorin ati Abraham Image copyright @trafficwaka

Kaka kewe agbọn ija laarin gbajugbaja oṣere sinima ede Yoruba, Toyin Abraham, ati ojugba rẹ Lizzy Anjorin dẹ, pipele lo n pele sii gẹgẹ bi awọn ololufẹ wọn ṣe ti gbe e ru sori tiwọn naa bayii.

Laipẹ yii ni ija naa bẹ silẹ laarin Toyin ati Liz. Ija ọhun bẹrẹ ni igba ti Lizzy Anjorin fi fidio kan lede loju opo instagram rẹ, nibi ti o ti fi ọpọlọpọ eebu ṣọwọ si Toyin.

Ọrọ naa lo ti da awuyewuye silẹ ti Toyin si ti fi ọrọ yii lọ agbejẹro rẹ, Legal House Solicitors.

Lẹyin eyi ni awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ oṣere nilẹ Yoruba bii Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy, wọn n gbiyanju lati dasi aawọ naa.

Ni bayii, awọn ololufẹ awọn oṣere wọnyi lo ti n sọ erongba tiwọn lori ẹrọ ayelujara.

Kini awọn eeyan n sọ?

Yemi Oketunji sọ loju opo Twitter rẹ pe, ọrọ alufansa ti Lizzy n sọ si Toyin fi han pe awọn obinrin kii ṣe atilẹyin fun ara wọn. O ni "Iṣubu ara wọn ni wọn n wa."

Ẹlomiran, AllthingsCy, loju opo Twitter tirẹ ni, bo tilẹ jẹ pe oun kii wo sinima Yoruba, sugbọn o jẹ oun itiju bi awọn gbajumọ mejeji yii ṣe n bu ẹnu ẹtẹ lu ara wọn lori ẹrọ ayelujara, ati pe, kii ṣe oun to dara ki wọn pe ara wọn ni ọmọ ale.

Awọn ololufẹ Toyin Abraham

Ololufẹ Toyin kan ni, bi Lizzy Anjorin ṣe n nọ'ka abuku si Toyin ti jẹ ki oun ni ifẹ Toyin ju ti atẹyinwa lọ. Ẹni miran lara awọn ololufẹ Toyin pa arọwa si i pe, ki o tiraka lati pari aawọ to wa laarin oun ati Lizzy.

King Kelvin, to jẹ ololufẹ Toyin ni tirẹ ni, oye ki Toyin gbe ọrọ arabirin Anjorin ti sẹgbẹ kan, nitori iti ọgẹdẹ ni.

Christiana Anuoluwapo naa sọrọ, o ni o " dara bi Toyin ṣe fi ọrọ naa lọ agbẹjọro rẹ, nitori igbesẹ to yẹ ki ẹni to kawe gbe ni.

Image copyright Insatagram/lizzyanjorin

Rhoda Owolabi to jẹ ololufẹ Toyin naa ko gbẹyin, o sọ pe ki Toyin fi ija f'Ọlọrun ja, nitori ija kii bi ọmọ ire.

Khalissa ni tirẹ ni, o yẹ ki Toyin gbe Lizzy Anjorin lọ ile ẹjo ni, nitori, ẹnu orofo Lizzy lo fẹ koba.

Image copyright Insatagram/lizzyanjorin

Awọn ololufẹ Lizzy Anjorin

Tawakalitu Lawal to jẹ ololufẹ rẹ bu ẹnu atẹ lu bi Lizzy ṣe n sọrọ alufansa si ojugba rẹ ninu iṣe sinima. O ni ko yẹ ki iru ẹni to wa ni ipo bi Lizzy maa lo ẹrọ ayelujara lati bu ẹlomiran.

Chidmma Nwokeji fesi loju opo Instagram Lizzy pe, awọn ololufẹ Lizzy kan n tan an jẹ lasan ni, ati pe Lizzy ti dagba kọja iru ẹni to yẹ ki o maa bu ẹlomiran lori ẹrọ ayelujara.

Arikeade Daranijo naa bu ẹnu atẹ lu Lizzy lori ọrọ yii, o ni awọn ogun idile Lizzy lo n tẹle lẹyin lo jẹ ko maa bu Toyin, o wa gbadura fun ki ẹnu rẹ ma ko ba a.