'South Africa tẹ́ wa lọ́rùn bẹ́ẹ̀, àwa ò fẹ́ wá sílé rára torí ...'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

South Africa: Ẹ rọ gbogbo àwọn ọmọ Naijiria tó ku láti wálé.

BBC

Ọkan nínú àwọn tó dé sí orílé èdè Naìjiria sọ̀rọ̀ ill kún lóri ǹka ti ojú rẹ̀ rí ní oríle-èdè Soouth Africa.

Janet Bolanle sàlàye fún BBC lásìò tó balé si pápákọ ofurufu nílùú Eko, ó ni kìí ṣe àwọn ọmọ Naijiria lo n ba South Africa jẹ́ bi ariwo ti wọ́n ń pa kíri bíkò ṣe ìdàkejí.

O ní ó sàn kí àwọn ẹbi pàrọwa si ẹbi wọ́n to wà nibẹ láti pada wálé nítori ọ̀rs ìkọlu náà kii ṣe ohun to le pari ní àsìkò yìí.

'South Africa tẹ́ wa lọ́rùn bẹ́ẹ̀, àwa ò fẹ́ wá sílé rára torí ...'

Ìbẹ̀rù ọgbà ẹ̀wọ̀n, àìsí ìdánilójú ìgbé ayé rere ni kò jẹ́ kí á fẹ́ wá sí Nàìjíríà báyìí, àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kù ní SA ṣàlàyé.

Ni alẹ Ọjọru, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹsan ọdun 2019 ni iṣi keji awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gbe ni orilẹede South Africa to pada wale nitori ikọlu awọn ajeji lorilẹede naa gunlẹ si papakọ ofurufu Muritala Mohammed ni ilu Eko.

O le diẹ ni ọọdunrun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn ba baalu Air peace to ko wọn wa de.

Amọṣa, pẹlu bi ikọlu naa ṣe gbona janjan to, ti ileeṣẹ irinna ofurufu Air Peace naa si tun fi anfani baluu ọfẹ silẹ fun awọn eeyan lati wale lọfẹ, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko wale.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu Ọgbẹni Jẹlili Elegbede, o ni aimọ bi oju ọjọ yoo ṣe ri fun awọn ati ẹbi wọn kun ara idi ti oun ko tii fi gbera wa sile o.

Ọgbẹni Elegbede ni lootọ ni o wu awọn lati wale ati lati sa asala fun ẹmi oun, ṣugbọn "gbogbo eeyan lo mọ pe orilẹede Naijiria ko dẹrun. Gbogbo wa la mọ bi a ṣe fi ile si."

Bakan naa ninu ọrọ tirẹ, Ọgbẹni Tọla ṣalaye pe ko si ẹni ti ko wu lati kuro ninu ewu to gbode ni orilẹede South Africa ṣugbọn ero lọbẹ gbẹgiri. Ọgbẹni Tọla ṣalaye pe onikaluku ti n tun ile rẹ to lati palẹ ile mọ.

Image copyright Getty Images

Arakunrin Oluwatuyi Damilọla ni tirẹ ṣalaye pe kudiẹkudiẹ ijọba orilẹede Naijiria lo ṣokunfa bi ọpọ ọmọ Naijiria to fẹ wale ko ṣe lee ba baluu naa wa. O ni yatọ si pe awọn kan ti ni ile, ọmọ ati dukia ti wọn gbọdọ kọkọ ṣeto fun ki wọn to wale, ọpọ to fẹ wale lo yipada ni papakọ ofurufu nigba ti wọn ri i pe gbogbo awọn ti ko ni iwe igbelu ni awọn alaṣẹ ilẹ South Africa n ko lati papakọ ofurufu lọ sinu ẹwọn. Ko si si ẹni to fẹ ṣẹwọn ninu wọn"

Ọgbẹni Oluwatuyi ṣalaye pe bi a ṣe n sọrọ yii ko din ni ọgọfa awọn ọmọ Naijiria ti awọn alaṣẹ South Africa ko lati papakọ ofurufu nibi ti wọn ti wa pade baluu Air peace ti yoo ko wọn pada wa sile ṣugbọn to jẹ pe inu ẹwọn ni wọn wa bayii lẹyin ti wọn ni wọn ko ni iwe igbelu.

Lori ohun ti oju wọn ri, awọn ọmọ Naijiria ti wọn ṣi wa lorilẹede South Africa ṣalaye pe ijọba orilẹede South Africa ko daabo bo awọn ajeji lasiko ikọlu naa gẹgẹ bi wọn ṣe n pariwo lori afẹfẹ.