Otedola Bridge:Ọkọ́ agbépo jábọ́ ní pópónà Èkó!

Otedola Bridge Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ igba ni ọkọ nla ma n jabọ ni opopona naa, ti o si ma n fa ijamba ọkọ tabi sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Ọkọ nla to kun fọfọ pẹlu ẹpo bẹntiroolu ti subu si opopona Ọtẹdọla ni ilu Eko.

Ajọ eto allbo oju popo ti wa nibẹ ni pẹsẹ ti wọn si n ko epo naa ki o ma ba a gbina.

Bakan naa ni wọn ni igbiyanju n lọ lọwọ lati ko ọkọ naa kuro loju popo, ki ọkọ le ma a lọ lọwọọwọ.

Amọ eyi ti da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ni oju popo naa.