Prince Harry: Ẹ má pa ìyàwó mi bí ẹ ṣé pa màmá mí

Prince Harry Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Meghan Markle tó fẹ Ọmọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi, Harry ti gbé ilé isẹ́ ìròyìn Mail lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìbànilórúkọjẹ̀.

Ọmọọbakunrin Ile Gẹẹsi, Harry ti ke gbajari lori bi awọn ileeṣẹ iroyin ṣẹ n gbe iroyin ẹlẹjẹ lori iyawo rẹ, Meghan Markle.

Harry ni oun bẹru pe ki oun to pa iya oun ma sẹlẹ si iyawo oun pẹlu bi awọn oniroyin ko ṣẹ fi wọn silẹ lati ọjọ ti oun ti fẹ.

Bakannaa Meghan ni oun yoo gbe ile iṣẹ iroyin Mail lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn n gbe lẹta ti oun kọ si baba oun sita lai gba asẹ lọwọ oun.

O fikun wi pe wọn ṣẹ afikun ati ayọkuro si lẹta ti wọn gbe jade wi pe oun kọ sinu lẹta ti oun kọ si baba oun kete ti o bẹrẹ si ni fẹ ọmọbakunrin Harry.

Amọ ile iṣẹ iroyin naa ni awọn duro gbọingbọin ti iroyin ti awọn gbe jade, ti awọn si ṣẹ tan lati koju wọn ni ilẹ ẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBlacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe

Related Topics