UFC 243: Isreal Adesanya sán bàǹtẹ́ ìyà fún Robert Whittaker pẹlu 18-0

Isreal Adesanya Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isreal Adesanya tó jẹ́ ẹni ọgbọ́n ọdún ló lu Robert Whittaker ní Melborne, Australia.

Ọdun meji ati ija meje pere ni Afẹsẹkubiojo Isreal Adesanya to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ati Australia lo lati gba Ami Ẹyẹ UFC.

Adesanya ti wọn n pe ni "Last Stylebender" lo gba Ami Ẹyẹ naa lẹyin to la Robert Whittaker mọlẹ, ni asekagba Idije UFC Middleweight Champion to waye ni Australia.

Adesanya na ikeji rẹ pẹlu 3:33 ni iwaju awọn eniyan to to ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta ni papakọ ere idaraya naa.

Lasiko to n sọrọ nipa aseyori rẹ, Adesanya ni ọpọ igba ni awọn eniyan ti ma n mu imu oun sẹjẹ, sugbọn ni bayii oun ti mu imu Whittaker naa sẹjẹ.

Aseyori yii jẹ ko jẹ igba mejidinlogun (18-0) ti afẹsẹkubiojo Adesanya ti jawe olubori to si fi gba Ami Ẹyẹ UFC Middleweight Champion.

Related Topics