"Akeredolu fọwọ́ òsì júwe ilé fún Pelemọ torí ..."

Rotimi Akeredolu Image copyright facebook page
Àkọlé àwòrán Gomina Ipinle Ondo Rotimi Akeredolu

Ẹni ti o jẹ oluranlọwọ gomina Ipinlẹ Ondo lori ọrọ eto iroyin, Ojo Oyewamide ti tanmọlẹ si ọrọ bi Akeredolu ṣe yọ oṣiṣẹ rẹ kan nipo.

Ọsẹ to kọja ni gomina Ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu fi ọwọ osi juwe ile fun ọkan lara awọn Olubadamọnran rẹ, Austin Pelemọ.

Austin Pelemọ lo ṣi ọrọ sọ lori ẹrọ ayelujara nigba ti o n ki aya lgbakeji gomina, Arabinrin Ajewọle Agboola Ajayi fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni ọjọ Aje.

Olubadamọnran naa lo pe aya Igbakeji gomina naa ni Adele Iyawo gomina ti o si da ede aiyede silẹ ninu ijọba naa latari ọrọ ti o sọ.

Nigba ti Ile Iṣe BBC nfi ọrọ wa a lẹnuwo, o ṣalaye o ni bo tilẹ jẹ pe oun ko si ni orilẹede yii nigba ti gomina naa fi ọwọ osi juwo ile fun oun, ṣugbọn gbogbo rẹ yoo ni abojuto.

O tẹsiwaju pe, oun yoo pada de ni opin ọsẹ yii, nigba naa ni oun yoo mọ lootọ boya gomina naa yọ oun, tabi ahesọ lasan ni.

Ṣe ninu ọrọ ti kọmiṣona fun eto iroyin ni Ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo fi lede lọjọ lsinmi Ọsẹ yii, lo ti ni lọgan ni ijọba ti yọ Pelemọ nipo bi ẹni yọ jiga.

Ninu ọrọ ti o sọ yii, ni awọn ero iwoye ti sọ wi pe, o fẹ da wahala silẹ ninu Iṣejọba Akeredolu nigba ti o ba n pe iyawo igbakeji gomina ni, adele iyawo gomina.

Ninu ifọrọ jomi tooro ọrọ pẹlu, Ojo Oyewamide ti o jẹ Olubadamọnran lori eto iroyin fun gomina naa ṣalaye pe, iru ọrọ bẹẹ ti pọju fun un lati sọ.

Oyewamide sọ siwaju si pe, o ti pẹ ti Pelemọ ti n gun igi rekọja ewe ṣugbọn ti gomina n fori ji i, latari pe yoo yi pada.

Ṣe ni nkan bii Oṣu meloo sẹyin ni gomina naa yọ awọn kọmiṣọna rẹ mẹta ti o si fun wọn ni iwe gbele ẹ naa.

Bakan naa ni a gbọ wi pe Agbẹjọro rẹ, Tolu Babalẹyẹ ti ni gomina kọ lo sọ bẹẹ nitori, gomina wa ni aaye isinmi.

O tẹsiwaju pe, ẹni ti o wa ni aaye isinmi ko le le Olubadamọnran rẹ lasan bẹẹ yẹn.