Ondo Flood: Fásitì gba òmùwẹ̀ àti fijilanté láti wá akẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ̀kún omi gbé lọ

Ile kan ti ẹkun omi wọnu rẹ Image copyright @Mr_Dami_

Baba akẹẹkọ Fasiti Akungba ti ẹkun omi wọ lọ ti sọ wi pe oun gbagbọ pe ọmọ oun ko ku sinu ẹkun omi to ya wọ ile naa.

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Baba Oladoyin Boluwaji ni adura ni ki awọn eniyan o ba oun gba, nitori oun gbagbọ pe ọmọ naa si wa laaye.

Baba Boluwaji wa ke gbajare si ile ẹkọ naa lati gbe igbesẹ to yẹ, ki wọn tubọ si tẹsiwaju lati wa a, nitori oun mọ pe ọmọ oun ko sọnu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fásitì gba òmùwẹ̀ àti fijilanté láti wá akẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ̀kún omi gbé lọ

Wayi o, Alukoro Ile Iwe Giga Akungba, Victor Akinpelumi, lasiko to n salaye aayan ile ẹkọ fasiti ọhun lati sawari Ọladoyin, o ni ẹkun omi si wa kaakiri agbeegbe naa ,eleyii to jẹ ki wọn gba iranwọ awọn omuwẹ lati tẹsiwaju lati ma a wa ọmọbinrin naa.

Awọn akẹkọọ ati alasẹ Ile ẹkọ fasiti Akungba pẹlu awọn omuwẹ lo ti parapọ lati wa oku ọmọ ti ẹkun omi gbe lọ ni Akungba.

Image copyright AAUA
Àkọlé àwòrán Ekun omi yale ni Akungba

Alukoro Ile Iwe Giga Akungba, Victor Akinpelumi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ sọ wi pe, awọn ko i ti ri iru ẹkun omi yẹn ri, nitori o mi eniyan ni iduro ni.

Akinpelumi ni, awọn ọga ile iwe naa gba awọn omuwẹ ati fijilante lati wa ọmọ naa, ti wọn si n wa lọwọ bayii.

Ninu ọrọ rẹ, o ni wọn ti fi to awọn obi ọmọkunrin naa leti, ti baba rẹ si ni igbagbọ pe won yoo ri ọmọ naa.

Image copyright @Mr_Dami_

Alukoro fasiti Adekunle Ajasin fikun wi pe, awọn ara ile ti isẹlẹ naa ti waye n tiraka lati sa asala fun ẹmi wọn nigba ti ogiri ya lulẹ, ti ẹkun omi naa si wọ ọmọ naa lọ.

Ẹkún omí gbé ọmọ fásitì Akungba lọ

Ọmọ ile iwe Fasiti Adekunle Ajasin ni ilu Akungba ni o ti di oloogbe latari ojo arọọrọda ti o ṣẹlẹ.

Ọmọ Fasiti naa ti orukọ rẹ n jẹ Oladoyin Boluwaji Tunrayọ ti o si ti wa ni ipele kẹrin eto ẹkọ rẹ ni iku ojiji naa wọle tọ ti o si se ẹmi rẹ legbodo ni ọjọ Aje Ọsẹ yii.

Ninu ọrọ ti Alukoro ile iwe naa, Victor Akinpelumi fi ṣọwọ si ile isẹ BBC ni o ti ṣalaye pe, gbogbo ipa ni wọn n sa lati ri oku ọmọ naa.

O ṣalaye siwaju sii pe, ojo naa pọ lọpọlọpọ to bẹẹ gẹ ti o ya wọle ibi ti ọmọ naa n gbe ti o si ya ogiri ile naa lulẹ ti o si gbe akẹkọọ ọhun lọ.

Gbogbo awọn alaṣẹ ati ọludari ile iwe naa ni wọn ti n sa hilahilo kiri lati wa oku akẹkọọ naa ri ninu agbara omi naa.

Ninu alaye ti Alukoro naa se, o wi pe igbakeji oludari ile iwe ọhun, ọjọgbọn Francis Gbore ati baba ọmọ naa to fi mọ awọn ọmọwe ile iwe ti bẹrẹ si nii ṣe akitiyan.

Image copyright AAUA
Àkọlé àwòrán Ibi ti agbara naa gba koja

Akinpelumi ni pe, ni asiko ti wọn ṣi n wa oku ọmọ naa, n ṣe ni gbogbo oju ọna kun fun omi ti gbogbo eniyan si n fa ṣokoto soke wọ inu omi naa.

O wa ni alaṣe ile iwe naa ti kan si awọn ajọ ti o ri si ọrọ pajawiri [NEMA] lati tete wa fun iranlọwọ ile iwe naa ni ṣiṣawari oku tabi aaye akẹkọọ naa.

Gbogbo akitiyan lati ri baba ọmọ naa sọrọ loja si pabo sugbọn ti awọn ọlọpaa si ṣe aridaju rẹ.