Sex for marks: Ilé aṣọ̀fin àgbà ń gbèrò ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá fún olùkọ̀ tó bá dẹnu ìfẹ́ kọ akẹ́kọ́

Boniface Igbeneghu

Ile aṣofin agba orillẹede Naijiria ti gunle aba kan ti yoo dẹkun bi awọn olukọ Fasiti ṣe n dẹnu ifẹ kọ awọn akẹkọbinrin.

Igbesẹ yii lo waye nile igbimọ aṣofin agba lẹyin ti ilẹeṣẹ BBC gbe fiimu kan jade, leyi to tu asṣiri awọn olukọ Fasiti kan lorilẹede Ghana ati Naijiria, ti wọn gbiyanju lati ba awọn akẹkọ ni ibalopo.

Igbakeji aarẹ ile aṣofin naa, Sẹnetọ Ovie Omo-Agege sọ pe, oun gbagbọ pe iwadii ti ileeṣẹ BBC ṣe yoo ṣe atilẹyin fun aba ọhun.

Omo-Agege ṣalaye pe gẹgẹ bi abiyamọ, oun ko faramọ bi awọn olukọ Fasiti sẹ n dẹnu ifẹ kọ awọn akẹkọbinrin.

Abadofin naa ti wọn ka nile igbimọ aṣofin n pe fun ẹwọn ọdun marun un si mẹrinla fun olukọ ti ọwọ ba tẹ pe o n ni ibalopọ pẹlu awọn akẹkọọ.

Ti awọn aṣofin naa ba gba abadofin yii wọlẹ, o tumọ si pe yoo jẹ eewọ fun olukọ Fasiti lati dẹnu ifẹ kọ awọn akẹkọ lorilẹede yii.

Fasiti Ghana ati Fasiti ilu Eko ti ni ki awọn olukọ ti oju wọn han ninu fidio naa ti BBC gbe jade lọ rọkun nile fun igba diẹ, titi ti wọn yoo fi ṣe iwadi ọrọ ọhun.

Àkọlé fídíò,

Palmwine Tapping: Ọ̀dọ́mọdé àdẹ́mu ní ìṣẹ́ náà kò wú òun lórí