Childbirth in Nigeria: Dokita àti Nọ́ọ̀sì ń fìyà jẹ àwọn alaboyún lásìkò ìbímọ!

Nọọsi
Àkọlé àwòrán,

Dokita àti Nọ́ọ̀sì ń fìyà jẹ àwọn alaboyún lásìkò ìbímọ!

Abileko Taiwo Gabriel ti ni awọn dokita, nọọsi ati awọn onisẹ abẹ lo fi iya jẹ oun lasiko ibimọ ni ipinlẹ Eko.

Eyi ko sẹyin bi Ajọ Ilera Lagbaye, W.H.O. ṣẹṣẹ gbe jade pe ogunlọgọ awọn alaboyun lorilẹ-ede Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede kọọkan nilẹ Afirika ni wọn máa n fi iya jẹ lasiko iloyun ati ibimọ.

Arabinrin Taiwo naa ni bi o tilẹ je wi pe oun ti bẹrẹ si ni jẹ irọra atirọbi, ni se ni awọn eleto ilera fi oun silẹ fun ọpọlọpọ wakati pẹlu irọra ko to wa di wi pe wọn da oun loun.

Lasiko ti wọn n sisẹ abẹ fun obinrin naa, awọn onisẹ abẹ, Dokita ati Nọọsi n fi oun wo fiimu lori ẹrọ amohunmaworan ko to di wi pe wọn wa ṣe isẹ abẹ fun oun.

Àkọlé àwòrán,

Àjọ Ìlera lágbàyé, WHO ti ní ènìyàn kan nínú aláboyún mẹ́ta ní àwọn eletò ìlera ma ń fìyà jẹ lásìkò ìbimọ ní Naijiria.

Abileko Taiwo fi kun un wi pe ijiya ti wọn fi jẹ oun lasiko ibimọ naa jẹ ki oun dubulẹ aisan lẹyin ibimọ, eleyii ti o si da irẹwẹsi ọkan si oun lara nitori irora ati ifiyajẹni ti oun la kọja lasiko naa.

Àkọlé àwòrán,

Opo iya lo maa n jẹ abiyamọ lasiko irọbi nitori pe awọn Noosi ko ki n tete dahun

Kini àwọn Nọọsi ri si ọrọ yii?

Ninu ọrọ tirẹ, Nọọsi Similoluwa Olabode ni oun ti ko tọna rara ni ki nọọsi ma a fi iya jẹ alaboyun lasiko ibimọ.

Amọ o fikun un pe, o seese ki awọn alaboyun naa ma tẹle asẹ awọn nọọsi tabi dokita ki ibimọ naa le rọrun fun wọn.

Nọọsi Olabode naa wa parọwa si awọn akẹgbẹ rẹ lati mọ daju pe awọn naa le wa ni ipo ti awọn obinrin naa wa lọla, nitori naa ki wọn huwa si wọn gẹgẹ bi eniyan bi ti ara wọn.

O ni irọbi jẹ laarin aye ati ọrun ni eyi ti ko yẹ ki oṣiṣẹ eleto ilera tun maa na wọn tabi pariwo mọ wọn lasiko irọbi rara.

Àkọlé fídíò,

Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́