Amnesty International- 119 ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n ti ṣe ìdájọ́ ikú fún lórílẹ̀-èdè Malaysia

Afurasi ni ahamọ ọlọpaa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O le ni ọgọrun ọmọ Najiria to wa lẹwọn ni Malaysia

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti gba idajọ iku ni Malaysia- Amnesty International.

Amnesty International ni ọmọ Naijiria mọkandinlọgọfa ni wọn ti fi sahamọ pe ọjọ iku wọn ko ni pẹ de.

Ajọ Amnesty International ti gbe iroyin kan jade to sọ pe, ninu awọn eeyan to le lẹgbẹrun kan ti wọn ti ṣe idajọ iku fun lorilẹ-ede Malaysia, o le ni ọgọrun un ọmọ Najiria to wa lara wọn.

Iroyin naa ti akọle rẹ n jẹ "Fatally Flawed" ni, ninu awọn eeyan ọhun to wa lẹwọn, ida mọkanlelogun ninu wọn jẹ ọmọ Naijiria.

Amnesty International lo gbe iroyin yii jade lọna ati tan imọlẹ si bi orilẹ-ede Malaysia ṣe n gbiyanju lati ṣe adinku si idajọ iku lorilẹ ọhun.

Ni orilẹ-ede Malaysia, ẹsun mẹtalelọgbọn ni eeyan lee gba idajọ iku le lori.

Iroyin ọhun ni, awọn ọmọ Naijiria to wa lẹwọn ni Malaysia ni ọwọ tẹ lori ẹsun gbigbe oogun oloro.

Ni oṣu kẹwaa, ọdun 2018 ni orilẹ-ede Malaysia kede pe oun n ṣe abadofin kan, eyi ti yoo fopin si idajọ iku.

Amnesty International ni oun lero pe orilẹ-ede Malaysia yoo fi opin si idajọ iku lorilẹ-ede ọhun laipẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTwin Festival 2019: Ṣé ọbẹ ìlasa àti àmàlà ló ń ṣokùnfà bíbí ìbejì ní ìlú Igboọrà?