BUSA 2019: Aisha Buhari ń hù ìwa ipá sí wa!- Ọmọ Mamman Daura

Image copyright TWITTER
Àkọlé àwòrán Ní ìpin ọ̀sẹ̀ ni fídíò ibi tí ìyàwó Ààrẹ Buhari, Aisha Buhari ti ń pariwo pé kí wọ́n sí ilẹ̀kùn ilé fún òun.

Lọsẹ to kọja ni iroyin kan kaakiri ori ayelujara pe Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ ṣe igbeyawo keji ti awọn eniyan si fẹ mọ nipa Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?

Lẹyin eyi ni ọpọ ọmọ Naijiria ba Aarẹ Buhari ṣeto igbeyawo ofegenaa lori ayelujara Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára

Ni ọjọ Eti ti awọn eniyan gba pe Aarẹ Buhari fẹ gbe minista Sadiya Umar Farouq ni iyawo ni Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó òfegè Buhari.

Opọ ni wọn n woye nipa arabinrin Sadiya ati oun to n ṣẹlẹ ni Aso Rock Èmi kò sí nílé, ọkọ́ mi ló leè sọ bóyá lóòtọ́ọ́ ló fẹ́ gbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha fèsì .

Ninu gbogbo iṣẹlẹ iroyin igbeyawo ofege Aarẹ Buhari yii ni fidio kan ti n tan kalẹ pe wọn ti ti Aisha Buhari mọle ninu ile ijọba ni Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC: òfin NYSC ti APC fi mú mi ni wọ́n kò lò fi mú Ajimọbi tí a kò jọ sìnrú ìlú

Kini fidio yii da le lori?

Ninu fidio yii ni afihan Aisha Buhari to jẹ aya Aarẹ Buhari lasiko to n binu to n sọ pe wọn ko jẹ ki oun wọ aaye naa ninu ile ati pe ko si nkan ti awọn agbofinro to le ni igba to wa nibẹ ri ṣe si ohun to n ṣẹlẹ.

Nigba ti BBC beere nipa fidio yii ni iwadii fihan pe Fatima Daura lo ya fidio naa.

Fatima, Ọmọ Mamman Daura ni pe oun lo ya fidio naa nigba ti o n ba akọroyin BBC sọrọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNo reception wedding: Adewale ni àpèjẹ kò ṣe pàtàkì sí òun

Fatima to jẹ ibatan Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni Iyawo Aarẹ, Aisha Buhari n hu iwa ipa ni Ile Aarẹ ni Ilu Abuja.

Fatima sọ eyi lasiko ti o n fesi si fidio ti o ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ni ọṣẹ to kọja lorilẹ-ede Naijiria.

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń jà?

Fatima ni oun lo ya fidio naa lasiko ti Aisha Buhari yabo Ile Glass House ti Aarẹ ti ni ki wọn kuro lati fi aaye gba itọju Yusuf, ọmọ Aisha ti o ṣubu lori kẹkẹ lasiko naa.

Arabinrin Fatima salaye wi pe, baba oun ati Aarẹ dabi tẹgbọn taburo ni, ti awọn si n gbe ni Ile Aarẹ lati bi ọdun melo ṣẹyin.

O ni ko ṣeeṣe fun ọlọpọlọ pipe lati gba pe wọn le tilẹkun mọ odindin aya Aarẹ orilẹ-ede ninu ile ara rẹ.

Image copyright @AishaBuhari
Àkọlé àwòrán Ọmọ Mamman Daura: Aisha Buhari ń wù ìwa ipá sí wa!

Kini Fatima sọ pe o ṣẹlẹ gangan?

Fatima ṣalaye kikun pe: "nibẹrẹ ni Aarẹ Buhari ti fun baba mi, Mamman Daura ni Glass House yii pe ki a maa gbe ti a si ti n gbe fun ọdun bii mẹta.

Ko pẹ ti o rẹ Yusuf ti wọn si gbe e lọ si Germany fun itọju lẹyin ijamba to ni lori alupupu rẹ.

Fatima Daura fi kun un wi pe kete ti Yusuf de pada ni Aarẹ ni ki Baba mi ko kuro ni Glass House lọ si ibo mii to tun tobi ni Aso Rock.

Aarẹ ni pe Yusuf a ko lọ si Glass House bi o ṣe pada de yii ki wọn le pese itọju to yẹ fun un nitori o sunmọ ibugbe iya rẹ, Aisha.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀

Fatima ni ohun to ṣokunfa fidio naa ni pe ẹbi oun ko tete ri aaye palẹmọ kuro ninu ile naa nitori ibi iṣẹ ni eyi ti oun ati ẹgbọn oun obinrin si wa ṣe ni ọjọ Abamẹta ọsẹ naa.

O ni ko pẹ ti a bẹrẹ ipalẹmọ ni Aisha Buhari yabo ile awọn ti o si fi aga ja ilẹkun, ti o si fẹrẹ kọlu ẹgbọn oun nibi ti o ti n huwa ipa si wọn.

Ti Aisha si bẹrẹ si ni pariwo si iyalẹnu gbogbo wọn.

Fatima ni idi ti oun fi ya fidio naa ni lati jẹ ẹri fun ọjọ iwaju nitori awọn ko mọ oun ti Iyawo Aarẹ naa le ṣe si awọn, nitori ara rẹ gbona gidigidi.

Opọ igba ni Aisha Buhari ti maa n sọrọ tako Maamman Daura lori ipa to n ko nile ijọba ni Abuja.

Ṣugbọn Fatima ni Buhari ati baba oun Daura wọnu nitori pe wọn jọ dagba papọ ni ti ọrọ wọn si ye ara wọn ni eyi ti ko dun mọ Aisha ninu lẹyin ti Buhari ti di Aarẹ .

Ọpọ iroyin lo n tan ni ayelujara pe Aisha gbagbọ pe Daura lo fẹ fẹ iyawo keji fun Aarẹ Buhari ni eyi ti wọn ni ko ri bẹẹ rara.

Igbiyanju wa lati ba awọn tile iṣẹ aarẹ sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ yii ko tii bi eso rere di asiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi