Poverty: Iyán àti ìse ń bá àwọn ọmọ Naijiria fín ra

Awọn obinrin to gbe ọmọ lọwọ Image copyright Getty Images

Awuyewuye ti n lọ lori ọrọ ti ijọba Naijiria sọ wi pe ko si isẹ ati iya ni orilẹede Naijiria nitori bijọba se ti gbogbo ibode to wa ni ẹkun Naijiria.

Minisita fun ọrọ ohun ọsin ati idagbasoke agbegbe, Sabo Nanono lo sọ bẹẹ ni Abuja nibi Ayajọ Ọjọ Ounjẹ ni Agbaye.

Minisita woye ọrọ yii lasiko to n fesi si awọn eniyan to bu ẹnu atẹ lu bii ijọba se ti awọn ẹnu ibode to wọ Naijiria, eleyii to dina karakata pẹlu awọn orilẹede miran, paapaa ounjẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nanono ni ẹrin ma a n pa ẹrẹke oun nigba kuugba ti oun ba gbọ pe ebi n pa awọn ọmọ Naijiria, nitori oun gbagbọ pe wọn ko mọ oun to n jẹ iya ati iṣẹ.

Image copyright Getty Images

Sugbọn nigba to n fesi si ọrọ yii, ajafẹtọ ọmọniyan kan, Daniel Akinlami sọ wi pe, ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun pe ijọba Naijiria ko mọ oun to n lọ ni ilu, paapaa iya ati isẹ to n ja rain nilẹ.

Akinlami ni awọn adari Naijiiria n se bi ẹni wi pe, iya to n jẹ awọn ara ilu ko kan wọn, nitori ọwọn gogo lo ba oun gbogbo ti awọn eniyan n ra ni ọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo fikun wi pe, ibode ti wọn ti pa naa fa ọwọn-gogo ounjẹ nitori awọn to n ta ounjẹ labẹle ti fi owo kun owo ọja wọn.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa wa parọwa si ijọba lati siju aanu wo awọn ara ilu, ki wọn si ibode naa, ki awọn eniyan le gbe igbe aye irọrun.

Bakan naa, awọn ọmọ Naijiria miran tun ti fi igbe ta ni oju opo ikansiraẹni BBC News Yoruba lori Facebook, ti wọn si n gbarata lori ọrọ ti minisita ọhun sọ pe ko si ebi ni Naijiria.

Ebi àti ìṣẹ́ kò sí ní Nàíjíríà, kódà a fẹ́ eré ìdárayá láti yọ́ ọ̀rá ara wa - Ìjọba àpapọ̀

Ijọba orilẹede Naijiria ti ni irọ lasan ni pe iya ati iṣẹ n ja rainrain lorilẹede Naijiria.

Minisita fun ọrọ ohun ọsin ati idagbasoke agbegbe, Sabo Nanono lo sọ bẹẹ ni Abuja nibi Ayajọ Ọjọ Ounjẹ ni Agbaye.

Minisita naa n fesi si awọn eniyan to bu ẹnu atẹ lu bii ijọba se ti ibode Naijiria, eleyii to dina karakata lati orilẹede miran, paapaa ounjẹ.

Nanono ni ẹrin ma a n pa ẹrẹke oun nigba kuugba ti oun ba gbọ pe ebi n pa awọn ọmọ Naijiria, nitori oun gbagbọ pe wọn ko mọ oun to n jẹ iya ati iṣẹ.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ọpọ̀lọ́pọ̀ àwọn omo Naijiria ló bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba se ti ibodè Naijiria láti dẹ̀kun gbígbé ẹrù wọ Naijiria.

O ni orilẹede Naijiria ni ounjẹ ajẹsẹku, nitorina ki wọn lọ si awọn orilẹede to wa ni ilẹ Afirika miran lati mọ ohun to n jẹ iya ati iṣẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Minisita naa ni awọn ọmọ Naijiria nilo ki wọn ma a ṣe ere idaraya lati le mu adinku ba ọra to wa ni ara wọn.

Amọ, Asoju Ajọ to n risi ọrọ ounjẹ lagbaye, Suffyan Koroma wa kesi ijọba lati mu ounjẹ wọpọ lorilẹede Naijiria, ki ebi ati iṣẹ le di ohun igbagbe.

Ogunjọ, Osu Kẹjọ, ọdun 2019 ni ijọba ti gbogbo ibode rẹ ni ẹkun mẹrẹẹrin to yii orilẹede Naijiria ka.