India: Àwọn ọmọ ilé ìwé fi páálí bojú láti má se jí ìwé wò!

India

Oríṣun àwòrán, ANI

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ènìyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ilé ìwé gíga fásitì ní Havari, lorilẹede india.

Osisẹ Agba ni Ile Iwe Giga lorilẹede India ti tọrọ aforiji lọwọ awọn eniyan, lẹyin ti aworan awọn akẹẹkọ to fi paali bori ja rainrain lori ẹrọ ayelujara.

Awọn aworan naa ni wọn ya lasiko ti awọn akẹẹkọ n kọ idanwo ni ile iwe fun awọn to fẹ wọ ile iwe giga Bhagat ni Haveri, ni India.

Awọn akẹẹkọ naa da paali boju pẹlu iho ni ẹgbẹ kan lati ma se jẹ ki awọn ọmọ naa ji ara wọn wo lasiko idanwo.

Osisẹ ile iwe naa parọwa si awọn obi wi pe awọn kan n woye boya paali naa yo dawọ asemase duro lasiko idanwo, eleyii ti awọn ọmọ ile iwe naa fi ọwọ si lati se e.

Wọn wa fikun wi pe awọn ti dẹkun lilo paali naa nitori bi awọn eniyan se bu ẹnu atẹ lu u.