Fulani Herdsmen Oyo: Bí ìjọba Ọyọ ba sún wa kan ògiri a mọ gbésẹ̀ to kan

Fulani ati Maalu ninu oko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán À ń gbé ìjọba ìpínlẹ̀ ọyọ lọ si ilé ẹjọ- Ẹgbẹ́ Fulani darandaran

Ogúnlọgọ̀ àwọn Fulani daradaran lo péju si ilú Ìgangan tó jẹ ilú ti àwọn àgbẹ pọ̀ si láti ṣe ìpàde pọ̀ lori àbádòfin tuntun ti ilé ìgbìmọ asòfin ipinlẹ Ọyọ

Lórí ìlòdì sí sínsin èràn tàbi kíko ẹ̀ràn jẹ̀ ní ìtà gbangba ní ìpínlẹ̀ Ọyọ èyí to ti wá si iwáju ilé fun ìgbà keji.

Abẹnugan ilé igbimọ aṣòfin ọgbẹni Adebo Ogundoyin àti ìgbakeji rẹ̀ Abiodun Fadeyi ni wọn jọ jumọpọ̀ gbé abadofin náà wá si iwáju ilé ni ǹkan bii ọ̀sẹ̀ méji sẹ́yìn.

Nínú ìpàdé àwọn Fulani ọhun ti olori wọ́n Sarkin Fulani ipinlẹ Ọyọ Alhaji Saliu Abdul-Kadir darí ni wọ́n ti sàpèjúwe abádofin náà gẹ́gẹ bii èyí ti ko dára rárá àti pé èrò ìkà ni àwọn to gbe àbá náà kalẹ̀, àti pé ọ̀ná láti mú ki àtijẹ ati mu àwọn Fulani nira ni.

O ní kò sí sise kò sí àìse il;e ẹjọ ni yóò yanju ọ̀rọ̀ náà, " A n lọ si ilé ẹjọ lati fopin si ááwọ̀ wa bi ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ba fi dandan mú wa lori òfin náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKengbe Ilorin: Àṣà ẹ̀yà Fulani, Bariba àti Gambari tó dàpọ̀ mọ́ ti Yoruba

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ akọwé àwọn Gan Allah Fulani Development Association, ọgbẹ́ni Graba Umar sàlàyé pe ẹgbẹ́ Fulani kọ ofin náà pátápáta nitori àwọn ri gẹ́gẹ́ bi èyí ti yóò mu ìfàsẹyin ba iṣẹ́ òòjọ àwọn pátápáta

Ẹ̀wẹ̀, Ẹgbẹ́ Fulani wá ni bí àbádofin náà yóò ba wá fi ẹsẹ̀ múlẹ, o di dandan kí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pèsè ilẹ miran fun àwọn láti maa ko mààlú si tí omi yóò si wà ni arọwọ́ to awọn.

Bí ìjọba ba wá kuna láti ṣe èyí, o túmọ si pé abadofin náà yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ ni.

Nínú ìwé àpérò ti wọ́n fi síta lẹ́yin ìpàdé náà ni wọ́n tun fi kún pe tìjọba Oyo ba le àwọn sún kan ogiri, àwọn mọ igbésẹ̀ miran ti awọn yóò gbe, èyí si ni lati lọ ile ẹjọ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde