Police Recruitment: Ìlé ẹjọ́ ti pàsẹ pe ki ilé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá dá ìgbaniwolé dúró

Awon olowo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Police Recruitment: Ìlé ẹjọ ti pasẹ pe ki ilé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá dá ìgbaniwolé

Ilé ẹjọ́ gígá nílùú Abuja ti pàsẹ pe ki àjọ ọlọpàá dá ètò ìgbànisísẹ́ ẹgbẹ̀run mẹ́wàá ti wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ dúró.

Adajọ Inyang Ekwo lofi idájọ náà jànlẹ pe ki wọ́n dááduro titi ti igbẹ́jọ́ tí ajọ ọlọpàá pe.

Eyi wáye lẹ́yin ti wọ́n so igbẹ́jó náà pọ̀ adájọ́ àgbà Abubakar Malami nínú ejọ náà.

Àwọn míràn ninu igbẹjọ náà ni Ọga agba ọlọpàá àti mínísita fun ọ̀rọ ọlọpàá.

Adajọ Ekwo ní gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kan ní a wọn gbọdọ tẹ̀lé ìdájọ náà titi yóò fi pari ọ̀rọ̀ naa.

Wàhálà ejọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ lásìkò tí àjọ ọlọpàá fẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n já ètò igbànisísẹ́ náà gbà mọ àwọn lọ́wọ́.

Àjọ ọlọpàá fẹ̀sun kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n ti tọ́wọ́bọ ètò àwọn ìgbàniwọle náà nipa àyípada àwọn orúkọ ninu iwé orukọ.

Tí ẹ o ba gbàgbé ètò ìgbaniwọlé ọlọpàá náà bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọdún to koja.

Àkọlé fídíò,

Òwe: Kí ni ìtumọ̀ òwe ikú tó ń pa ojúgbà ẹni?