Instagram yọ "Cosmetic Surgery Filters" dànù lórí ẹ̀rọ rẹ̀

Awọn to n lo Instagram

Oríṣun àwòrán, DANIEL MOONEY/INSTAGRAM

Ileeṣẹ Instagram ti wọgile "Augmented Reality (AR) filters," eyi to n ṣagbatẹru fun iṣẹ abẹ ikunra ẹni, lẹyin awuyewuye pe o lee ṣe ijamba fun ilera ọpọlọ awọn eeyan.

'AR' yii ti wọn tun n pe ni "Cosmetic Surgery Filters," to lee mu ki aworan eeyan da bi ẹni to ti ṣe iṣẹ abẹ ri, ni Instagram ti pinnu lati yọ danu kuro lori ẹrọ rẹ.

Instagram to jẹ ọkan gboogi lara awọn ileeṣẹ Facebook sọ pe, igbesẹ lati yọ ẹya yii kuro lori ẹrọ Instagram jẹ latari ifẹ ti ileeṣẹ ọhun ni si awọn to n lo ẹrọ naa.

O ni "a o yọ gbogbo ẹya to ni ṣe pẹlu iṣe abẹ ikunra ẹni kuro lori Instagram, a o si tun ṣe idaduro awọn ẹya miran to fara jọ iru rẹ."

Ni oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni ileeṣẹ ọhun fun awọn to n lo ẹrọ Instagram ni oriṣiriṣi ẹya to mu ko ṣeeṣe lati ṣe oun to ba wu wọn pẹlu aworan ati fidio wọn.

Lara awọn ẹya ọhun bii "Plastica" lo lee mu ki aworan eeyan dabi ẹni to ti ṣe iṣe abẹ ikunra ẹni ri.

Ileeṣẹ Instagram ti ni oun ko mọ akoko to le gba lati yọ awọn ẹya naa kuro lori ẹrọ rẹ, ṣugbọn ọpọlọpọ awọn to n lo ẹrọ naa faramọ igbesẹ ọhun.

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde