Sex for Grades: Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko fìwé pe olùkọ́ UNILAG Boniface Igbeneghu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Boniface Igbeneghu
Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi iwe pe Boniface Igbeneghu, to jẹ olukọ agba ni Fasiti Eko ti ọrọ kan lori fiimu fifi ibalopọ gba maaki ti ileeṣẹ BBC gbe jade laipẹ yii.
Igbeneghu to jẹ Pasitọ ijọ Foursquare Gospel Church ni fidio naa tu aṣiri rẹ, ni bi o ṣe gbiyanju lati fi ọrọ ibalopọ lọ akọroyin BBC to dibọn bi ẹni to ṣẹṣẹ fẹ wọle si Fasiti Eko.
Ninu iwe akọranṣẹ kan ti igbakeji ọga ọlọpaa Yetunde Alonge buwọlu ni wọn ti ni ki olukọ naa yọju si agọ ọlọpaa, ẹka D10 CID to wa ni Yaba.
- A ti mọ òbí 40 nínú 108 t'ọ́mọ wọn bọ́ ní ayédèrú ibùdó atúnwàṣe Ilorin - Ọlọ́pàá Kwara
- Mo pàṣẹ pé kí ọ̀gá owó ìfẹ̀yìntì tẹ́lẹ̀, Maina sì wà látìmọ́lé- Adájọ́
- Ó rẹ ẹni ọdún 49 tó ri ẹ̀wọ̀n ọgọ́ta ọdún he lẹ̀yìn tó bá ọmọ ọdún méjì lòpọ̀
- Ìgbà tí òògùn ẹ̀jẹ̀ ríru lè ṣiṣẹ́ jù rèé- Onímọ̀
- Wọ́n ti ṣí ilé oúńjẹ oní ọgbọ̀n náírà (N30) ní Kano
Alonge sọ pe Igbeneghu ko tii yọju si agọ ọlọpaa ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn fi iwe naa ranṣẹ sii nipasẹ Fasiti Eko.
Lẹyin ti BBC gbe fiimu ọhun jade ni Fasiti naa ni ki Igbeneghu lọ rọkun nile fun igba diẹ, latari ọpọlọpọ awuyewuye to tẹle fiimu naa.
Bẹẹ naa ni ijọ Foursquare Gospel Church sọ pe ki Igbeneghufi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi pasitọ ijọm ọhun.
Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde