Visa to Nigeria: Ó lé gba ìwé ìrìnnà (Visa) láti wá fẹ̀yìntì sí Naijiria

Ilé isẹ́ ìrìnnà Naijiria

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN IMMIGRATION SERVICE

Àkọlé àwòrán,

Ilé isẹ́ ìrìnnà Naijiria ti setán láti fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti má a wọ Naijiria fún ìfẹ̀yìntì.

Ile isẹ irinna lorilẹ-ede Naijiria ni awọn ti setan lati gbe orisirisi iwe irinna tuntun jade fun awọn eniyan.

Adari ile isẹ irinna naa, Mohammad Babandede lo sọ ọrọ yii nibi ipade awọn Ọga Agba irinna to waye ni Benin, lorilẹ-ede Naijira.

Babandede ni awọn ẹka ti yoo ma a gba iwe irinna naa ni awọn ti wọn fẹ wa gbafẹ, awọn ti wọn fẹ wa se karakata ati awọn ti wọn fẹ wa fẹyinti si orilẹ-ede Naijiria.

Eyi tumọ si wi pe Naijiria yoo bẹrẹ si ni fun awọn eniyan to wa ni ilẹ̀ okeere, ti wọn fẹ wa fẹyinti si orilẹ-ede Naijiria ni Iwe Irinna.

Osu Kefa, ọdun 2019 ni Naijiria bẹrẹ si ni lo iwe irinna to n lo ẹrọ ayelujara, eleyii ti yoo faye gba awọn eniyan lati lo iwe irinna wọn fun ọdun mẹwa, o si tun le woye ibi ti eniyan wa ni igba de igba.

Iwe irinna naa pin si ọna mẹta, ikan fun awọn ọmọ Naijiria, ikan fun awọn osisẹ pataki ati ikẹta fun awọn osisẹ pataki fun ijọba Naijiria.

Ọdun 2018 ni ọga ile isẹ irinna Naijiria sọ wi pe Osu Kejila, ọdun 2018 ni awọn eniyan yoo bẹrẹ si ni lo iwe irinna tuntun naa.

Amọ, o fikun un wi pe awọn to ni iwe irinna ti tẹlẹ naa yoo ni anfaani lati lo o, lai si idiwọ idena kankan.

Bakan naa ni Ọga Agba ile isẹ irinna Naijiria naa fikun wi pe ipa rere ni ibode Naijiria ti wọn ti ko lori ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria ati wiwọle-wọde awọn eniyan lati orilẹ-ede miran wa si Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN IMMIGRATION SERVICE

Àkọlé àwòrán,

Visa to Nigeria: Ó lé gba Visa láti wá fẹ̀yìntì sí Naijiria

Ọga Mohammad Babandede fikun wi pe o le ni ẹgbẹrun mọkanla eniyan ti wọn ti ọwọ ti tẹ lasiko ti wọn wa ọna lati kuro lorilẹede Naijiria lai ni Iwe Irinna to peye.