Ebi ló ń pami ti mo fi já sọọbu láti jí bisikitì- Afurasi Asuquo

Asuquo Destiny

Oríṣun àwòrán, @the News

Àkọlé àwòrán,

Ebi ló ń pami ti mo fi já sọọbu láti jí bisikitì- Afunrasi

Ẹni ọdun mẹẹdọgbọn kan, Destiny Asuquo ni ọwọ́ sìnkún ọlọpàá tí tẹ ni ìlú Port Harcourt lágbègbè Rumuodara ni ìpínlẹ̀ Rivers.

Awọn agbofinro mu u pe o jale ni ṣọọbu kan ni agbegbe naa.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Asuquo to n síṣẹ́ àtunṣe ọpa ẹ̀rọ omi (plumber) sọ lẹ́yìn ti ọ̀wọ́ tẹ̀ẹ́ lo ti sàlàye pé ọwọ́ ebi lo bá oun ti oun fi lo já sọ́ọ̀bù láti ji ẹlẹ́rìndodò àti bísikítí.

Àkọlé fídíò,

Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Asuquo ọmọ bibi ìpínlẹ̀ Akwa Ibom bẹ ẹni to ni sọ̀ọ́bù ti o já pé ki wọ́n fi orí jin òun ni èyi to sàlàyé pé ó mu ẹbi to n pa oun dinku.

Ní ààjìn ni ọwọ àwọn ọlọdẹ orú tẹ Asuquo ní àgbègbè Rumuodara lẹ́yìn to já sọọbu naa láti jẹ Gala, ẹlẹrindodo àti bisikiti.

Nígbà ti wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ni fi ọ̀rọ̀ wáa lẹ́nu wò, ọmọkunrin náà ni òun ko tii fi òunjẹ kan ẹnu fún ọjọ meji pẹ̀lú ìreti pé o yẹ ki oun rí iṣẹ́ gbà sùgbọ̀n ti kò yori.

Asuquo ní èyí lo tí oun láti já sọọbu náà láti rí ǹkan jẹ láti dóòlà ẹ̀mí oun nítori oun ní ọgbẹ́ inú tí o si ti n dàá láàmu fú odindi ọjọ́ meji.

Wọn ti fá afura si náà le ọlọpàá Okporo ni àgbegbe Rumuodara lọ́wọ́ fún ìwádìí.

Ẹ̀wẹ́, àwọn ẹgbẹ́ ajafẹ́tọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers ti ro àwọn ọlọdẹ ni àdúgbò Rumuodara láti rii dáju pé wọ́n o tẹ ofin ati ẹtọ àwọn ti wọn ba mú lóju mọ́lẹ̀.

Ogbẹni Prince Wiro to jẹ alaga ajọ awọn ajijangbara nipinlẹ Rivers ni wọn ko gbọdọ fiya aitọ jẹ afurasi naa rara.