Ann Grace Aguti: Obìnrin kan to fẹ́ ọkọ mẹ́ta lẹ́ẹkàn ṣoṣo

Oko ati Iyawo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ann Grace Aguti: Obìnrin kan to fẹ́ ọkọ mẹ́ta lẹkàn soso

Ọ̀rọ̀ òbìnrin kan tí bẹ̀rẹ si ni jà rànyìn-ranyin lórí ẹ̀rọ ayélujára lóri ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti fẹ́ ọkọ mẹ́ta lẹẹ́kan ṣoṣo.

Ann Grace Aguti ẹni ọdun mẹ́rìndinlógójì fẹ́ ọkúnrin mẹta, Richard Alich, John Peter Oluka àti Michael Enyaku ti gbogbo wọ́n si jọ ń gbe pọ.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn New Vision lo já ojú ọ̀rọ̀ náà lẹ̀yìn ti baba Aguti, olùsọ-aguntan Peter Ogwang lo kó àwọn ẹbi ẹ lọ láti le àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ jáde kuro nile.

Aguti to loyun osù mẹ́fa ti fún àwọn ọkọ rẹ ni ilé mẹ́ta nínú mẹje to wa ni àgbàlá rẹ̀.

Ìròyin sọ pe Aguti ni ọkùnrin to pọ̀ ninu àgbàlá náà sùgbọ́n o le gbogbo wọ́n nítori wọ́n o ni ìbáwí.

Aguti ti wa fèsì si ǹkan ti bàbá rẹ̀ ṣe láti lé àwọn ọkọ rẹ̀ kúrò nilẹ: "Mó lọ́kọ tẹlẹ̀, bí awọn ará ìlú mi ṣe fẹ́.

Àkọlé fídíò,

Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ

Sùgbọ́n ǹkan ti mo fẹ́ ni pé ki n ri ẹni ti yóò fẹ́ràn mi, tí yóò maa pèsè gbogbo ǹkan ti mo nilò. Ọkọ mí kò wúlò, emi si ni mo ń ṣeto jijẹ mimu.

Nígbà ti mo fi sílẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ si ni wá ẹni ti ọkan mi fẹ́"

Ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ Aguti ti sàlàye bi wọ́n se pade Aguti ni Uganda, Alich fẹ̀yìnti nínu iṣẹ́ ọlọpàá pẹ̀lú ọmọ mẹwàá to ti dàgbà.

Oluka ni àwọn jọ wá láti ìlú kan náà, sùgbọ́n òun mọ pé Aguti ni ọkùnrìn tó pọ̀.