Ìjọba ìpínlẹ̀ ÈKó ṣàwárí agolo ìkẹ́rù márùn ún tó kún fún ẹja tó ti díbàjẹ́

Agolo ikẹru Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ayẹwo naa ni ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri, LASEMA ati ajọ to n risi ọrọ itọju ayika, LASEPA ṣe ni ifọwọsowọpọ

Awọn oṣiṣẹ alabo ipilnlẹ Eko ti ṣawari agolo ikẹru marun un to kun fun ẹja to ti dibajẹ, ati awọn ounjẹ miran lagbegbe Apapa, nipinlẹ ọhun.

Iroyin ni wọn ṣawari awọn agolo ikẹru naa ni igba ti wọn ṣe ayẹwo lagbegbe ọhun, latari bi awọn eeyan kan ṣe n royin oorun buburu ni ọkan lara awọn ibudokọ ọkọ oju omi to wa nibẹ.

Ayẹwo naa ni ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA, ati ajọ to n risi ọrọ itọju ayika ipinlẹ Eko, LASEPA ṣe ni ifọwọsowọpọ.

Ninu awọn agolo akẹru merundinlọgbọn ti wọn ri, marun un ninu wọn ni awọn ohun jijẹ wa, ṣugbọn ti ẹrọ amu nkan tutu rẹ ko ṣiṣẹ mọ.

Ọga agba fun ajọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu ni awọn ẹja to ti dibajẹ yii ti ṣe ijamba fun awọn olugbe lagbegbe Trinity Close, ni Apapa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOwu Water Fall: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì