Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé

Yewande, Yetunde, Yejide, Iyabọ: awọn orukọ to mu itan da ni!

Ile la n wo ni ilẹ Yoruba ki a to sọ ọmọ lorukọ!

Iran Yoruba kii sọ ọmọ ni orukọ lai kọkọ wo nkan to n ṣẹlẹ ninu aye wọn, ninu ẹbi wọn ati ninu agboole wọn ki wọn to sọ ọmọ tuntun lorukọ.

Loni BBC Yoruba lọ wadii iru ọmọ ti Yoruba n pe ni Yetunde lẹyin ti a bii.

Yewande, Yetunde, Yejide, Iyabọ jé awọn orukọ ti a n sọ ọmọbinrin ti a bi lẹyin iku iya baba rẹ tabi ti iya iya rẹ.

Ti ọmọ naa ba jẹ ọmọ okunrin, Babajide, Babatunde, Babawale, Babarinde ni wọn n sọ ọ.