Local Government Service Commission: Ẹwo àwọn ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nipa àjọ yìí

Awọn oṣiṣẹ ijọba ni Ajọ to n mojuto ọrọ ijọba ibilẹ ni Oṣogbo

Oríṣun àwòrán, @excellent123

Àkọlé àwòrán,

Ẹka ileeṣẹ ijọba yii lo ma se idanilẹkọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ

Ajọ to n mojuto ọrọ ijọba ibilẹ ni Naijiria jẹ ẹka to n risi ọrọ to jẹ mọ iṣakoso ijọba ibilẹ, gẹgẹ bi ofin ṣe gbe e kalẹ.

Oriṣiriṣi ẹka lo wa ni ajọ yii, bi ẹka idanilẹkọ, ẹka iṣẹ iṣakoso, ẹka to n ṣagbega fun awọn oṣiṣẹ lẹnu iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iṣe ti ajọ yii n ṣe lati mu iṣejọba ibilẹ rọrun ko kere rara, ẹ jẹ ka wo diẹ ninu wọn.

Isẹ́ tí àjọ LGSC ń ṣe

Ajọ yii lo n ṣe igbanisiṣẹ oṣiṣẹ fun awọn oṣiṣẹ tuntun, igbega fun awọn to ti wa lẹnu iṣẹ tẹlẹ, pinpin oṣiṣẹ si ẹka ileeṣẹ ati ifiyajẹ awọn to ba n ṣe imẹlẹ lẹnu iṣẹ.

Ẹka ileeṣẹ ijọba yii kan naa lo ma n ṣe idanilẹkọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

Bakan naa, ajọ yii lo n yan awọn to n ṣamojuto eto iṣẹ ojojumọ nile iṣẹ ijọba ibilẹ.

Ni ti awọn dukia ijọba ibilẹ, ajọ yii naa lo n ṣamojuto wọn lati ri i pe wọn n ṣe deede.

Lara awọn dukia ijọba ti ajọ naa n mojuto ni; ọkọ ijọba, ẹrọ amunawa, awọn ọfiisi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ti ariyanjiyan ba waye laarin awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, ajọ yii ni ẹka to ga ju lọ, to ni ojuṣe lati pari aawọ naa.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé

Ajọ ọhun kan naa lo n mujuto gbogbo ohun to jọ mọ isimi ọlọdọọdun, ati awọn isimi miiran fun awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

Ko tan sibẹ, ajọ yii lo wa ni iṣakoso yiyi orukọ pada ati gbogbo ohun to jọ mọ itọju awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

Gomina ipinlẹ lo ma n yan alaga ajọ naa ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo si buwọlu orukọ awọn eeyan ti gomina yan, ni ilana ofin.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN