Ìjọ Kátólíkì bẹ̀rẹ̀ ìwáàdì lẹ̀yìn tí àwọn sisitá méjì lóyún ójijì

Awọn sista Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Pope Francis ti sọ ni ibẹrẹ ọdun yii pe, awọn Bisọbu kan ma n fi ipa ba awọn sista ni ajọṣepọ

Ijọ Katoliki ti n ṣe iwaadi bi awọn sista meji kan ṣe loyun lẹyin ti wọn lọ ṣe iṣẹ iranṣẹ nilẹ Afirika.

Awọn obinrin mejeji naa to jẹ olugbe ilu Sicily, lorilede Italy, ti wọn kii si ṣe ọmọ ijọ kan naa, ni wọn n duro de ọjọ ikunlẹ bayii.

Ọkan lara awọn obinrin ọhun, to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn lọ si ile iwosan nitori inu rirun, ki dokita to fun ni iroyin pe oyun ti duro sara rẹ.

Ijọ Katoliki to wa ni ilu Rome sọ fun awọn akọroyin pe, igba ti awọn obinrin naa rin irin ajo lọ si ilẹ adulawọ ni wọn ni ibalopọ.

Ijọ ọhun tẹsiwaju pe awọn obinrin naa ru ofin to jẹ mọ ẹsin ati iṣẹ ti wọn gba, bẹẹ ni iwadii ti bẹrẹ lori bi wọn ṣe di alaboyun ojiji.

Ni ibẹrẹ ọdun yii ni olori ijọ Katoliki lagbaye, Pope Francis ti sọ ṣaaju pe, awọn Bisọbu kan ma n fi ipa ba awọn sista ni ajọṣepọ, koda o ni wọn n fi awọn miran lara wọn ṣe ẹru ibalopọ.

Popu ṣalaye pe, bi awọn Biṣobu yii ṣe n ni ibalopọ pẹlu awọn obinrin naa jẹ isoro nla ninu ijọ Katoliki.