Ebola: NCDC ní àwọn ń sisẹ́ bí aago ni láti dènà Ebola ní Naijiria

Ebola Outbreak Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé Asòfin Àpapọ̀ ti se ìkìlọ̀ pé ó seése kí Naijiria lùgbàdì àìsàn Ebola tí wọ́n kò bá tètè mú ètò ìlerà lẹ́kùnrẹ́rẹ́.

Ajọ to n risi isakoso eto ilera ati igbogunti aisan lorilẹede Naijiria, NCDC ti ni lati osu mẹta sẹyin ni awọn ti bẹrẹ eto gbigbogun ti aisan Ebola lorilẹede Naijiria.

Ajọ NCDC sisọ loju ọrọ naa fun Yoruba lẹyin ti Ile Igbimọ Asofin apapọ kede pe o seese ki Naijiria lugbadi aisan Ebola, ti wọn ko ba tete mu eto ilera lọkunkundun.

Ile Igbimọ Asofin naa, nibi ijoko ile sọ wi pe ijọba ko karamaasiki eto gbigbogun ti aisan naa, ko ma baa wọ Naijiria, nitori ọdun 2018 ni wọn ti se eto ilanilọyẹ nipa rẹ sẹyin.

Amọ nigba to n fesi lori ọrọ naa, NCDC ni awọn osisẹ oun n sisẹ bii aago ni lati igba ti Ajọ Ilera lagbaye, WHO ti fi ikilọ lede pe, o seese ki ajakalẹ aarun Ebola bẹ silẹ ni awọn orilẹede to sunmọ orilẹede DR Congo, ti aisan naa ti n ja rain.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun naa ni, gbogbo eto lo ti to, lati ri wi pe Ebola ko ba awọn lojiji, ti aisan naa ba bẹ silẹ lorileede Naijiria.

Image copyright Getty Images

O fikun wi pe, ti ẹnikẹni ba gbe aisan naa wole si orilẹede Naijiria lati ilẹ miran, awọn n sisẹ pọ pẹlu awọn osisẹ ilera ni ẹnu ibode ati papakọ ofurufu Naijiria, lati tete dena iru ẹni bẹ ẹ ko mase wọ orilẹede yii.

Ajọ Ilera Lagbaye, WHO ni eniyan ẹgbẹrun lọna meji o le (2,123) lo ti ku lẹyin ti aisan naa tun bẹ silẹ lorilẹede D R Congo ni Osu Kẹjọ, ọdun 2018.