Sowore: Àwọn olùwọ́de gbé pátákó ìkéde lọ sí ọọ́físí àjọ ọ̀tẹ́lẹ̀múyẹ́

DSS Image copyright @KikelomoSowore
Àkọlé àwòrán Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS kọ̀ láti fi Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ gbà pàsẹ kí àjọ náà fi sílẹ̀.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti ni ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fi ọta ibọn ati afẹfẹ tajutaju le awọn afẹhonu han kuro ni olu ileesẹ wọn ni Abuja.

Awọn afẹhonu han naa, to n pe fun itusilẹ Sowore to ti wa ni atimọle ajọ DSS naa lati osu diẹ sẹyin, lo gbe iwọde wọn lọ si ọọfisi ajọ DSS naa lọjọ Isẹgun.

Awọn to n fehonu han naa yabo Ile isẹ DSS ni aarọ amọ ti wọn n lgun loju o[po Twitter pe se ni awọn osisẹ DSS naa da ibọn bolẹ lati le awọn kuro ni agbeegbe naa pẹlu afẹfẹ alata.

Fidio kan to wa lori ẹrọ ayelujara safihan bi ọta ibọn se n dun takotako eyi ti awọn osisẹ DSS n yin lati dẹru ba awọn eeyan to n fẹhonu han ọhun.

Image copyright @TheICIR

Amọ se ni awọn eeyan to n fẹhonu han naa n pariwo pe awọn osisẹ DSS ko lee pa gbogbo awọn tan bo ti wu ki wọn lagbara to.

Sugbọn ko pẹ, ko jinna, ti awọn afẹhọnu han na papa bora, ti wọn si fi gbogbo ẹru ti wọn fi n se ẹhonu naa silẹ, lati sa asala fun ẹmi wọn.