Seyi Makinde: Èmi àti àwọn èèyàn Ọyọ yóò máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun

Makinde Image copyright Makinde/Twitter
Àkọlé àwòrán Ipinlẹ Oyo yóò fọwọ́solwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọogun Nàìjíríà- Seyi Makinde

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fí èrò ọkan rẹ̀ han pé, ìjọba oun àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Oyo yóò tẹ̀síwájú láti maa fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà.

Makinde sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó péju síbi ayẹyẹ ìsíde idije ibọn yinyin laarin awọn ipẹẹrẹ ologun (NASAC), eyi to wáye ni ileesẹ ọwọ keji ologun ti Adekunle Fajuyi to wa ladugbo Odogbo, Ọjọọ, nilu Ibadan.

Image copyright Seyi Makinde

Makinde ní ìnú òun dún fun àyẹsí ti wọ́n fún oun, to si jẹjẹ pe oun ati awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ yoo tubọ maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn osisẹ ologun.

" Mo gbadúrà pé gbogbo àwọn akopa nínú ètò náà ni yoo se àṣeyọri, ti eto naa yoo si jẹ mánigbàgbé fun wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo."